Lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe etọ ọhun mu aṣeyọri jade nitori bawọn araalu ṣe n tu jade lati wa forukọsilẹ pẹlu awọn ilana ati eto ti wọn la silẹ fun.
Gẹgẹ bi akọwe olupolongo naa ṣe wi, o sọ pe ṣe lawọn eeyan naa forukọsilẹ pẹlu awọn ohun elo ti ofin ẹgbẹ pa laṣẹ pe ki wọn mu dani lati wọọdu kọọkan.
Awọn nnkan to sọ pe ẹgbẹ ni ki wọn mu dani ọhun ni orukọ wọn, ibi ti wọn n gbe, kaadi NIN wọn, kaadi idibo, ati ibi ti wọn ti maa n dibo gan-an.
Nuberu ṣalaye siwaju pe ẹnikẹni to ba wu lati darapọ mọ ẹgbẹ ni wọn n ṣe fun.Nitori nnkan to ni ofin ẹgbẹ sọ ni pe onikaluku lo ni ẹtọ lati darapọ mọ ẹgbẹ to ba wu u.
Bẹẹ lo sọ pe ẹnikẹni to ba ti jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun lo ni anfaani iforukọsilẹ yii pẹlu kaadi NIN, paapaa julọ ti kaadi idibo wọn ko ba tii yanju, o ni eto bi wọn yoo ṣee ṣe wa.
Akọwe olupolngo ọhun tun waa sọ bi awọn eeyan ṣe n jade si, o ni " Ṣe ni a n gbadura pe ki ọwọ wa le ka awọn to n jade fun eto yii, tẹlẹtẹlẹ eeyan kọọkan la fi si awọn wọọdu ti wọn ti n ṣe amọ nigba ta a ri bo ṣe n lọ si, eeyan mẹfa ni wọn n wa nibẹ bayii."
O ni sibẹ ero ṣi n tu jade gan an, eyi to mu inu oun dun, o waa sọ pe ipari oṣu yii ni eto iforukọsilẹ ọhun yoo pari gẹgẹ bi ẹgbẹ ṣe la fun wọn.
No comments:
Post a Comment