Ireti wa pe orileede Naijiria yoo tubọ dara ju bayii lọ- Sẹnetọ Gbenga Daniel - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 18 January 2026

Ireti wa pe orileede Naijiria yoo tubọ dara ju bayii lọ- Sẹnetọ Gbenga Daniel

Aṣofin Gbenga Daniel to n ṣoju ẹkun Ogun East, nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti sọ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọọ yii, o daju pe nnkan yoo pada bọ si rere lorileede, ti inu gbogbo mutumuwa yoo si dun.

O sọrọ yii nibi isin idupẹ ọlọdọọdun, ẹlẹkọkanlelogun iru ẹ to maa n ṣe ni ṣọọṣi Abraham Terbanacles, to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni pẹlu ojuwoye oun ati bi nnkan ṣe ri lakooko yii atunṣe rere ti bẹrẹ si nii de silẹ wa Naijiria.

O fikun ọrọ ẹ pe,lawọn akoko yii ọna abayọ ti n de ba ọpọ awọn ipenija ta a n koju lorileede yii paapaa julọ nipa eto aabo, ti gbogbo ẹ si ti n rọlẹ.

Daniel tun sọ pe " Ẹ jẹ ki a kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun lori bo ṣe n mu wa bori awọn ipenija ta a n koju lawọn bi akoko yii. O si da mi loju pe ninu ọdun tuntun yii, ọpọ iru nnkan bẹẹ ni yoo di ohun igbagbe.

Bakan naa lo tun sọrọ lori nnkan to sọ nipa awọn oloṣelu pe ole ni wọn, onirọ ni wọn, ṣugbọn oun dupẹ pe lati bi ọdun mẹtalelogun sẹyin, toun ti ṣejọba gẹgẹ bi gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun bẹẹ loun tun di awọn opo kan mu, ko si ẹni to le sọ pe eyi lọrọ toun sọ, to jẹ irọ, nitori idi eyi ki wọn mọ bi wọn ṣe dajọ.

Bẹẹ ni Daniel to tun jẹ oludasilẹ BAT/OGD movement, tun lo akoko naa lati rọ awọn araalu, lati dibo aarẹ wọn fun ẹni to ṣe fi ọkan tọ.

Ninu ọrọ ti Ọnarebu Ladi Adebutu bawọn oniroyin sọ nibi isin idupẹ ọhun loun tun ti sọ pe oun nigbagbọ pe ọjọ iwaju orileede yii yoo si dara pẹlu bawọn ipenija oriṣiriṣi ṣe n yọju.

O ni oun mọ pe Ọlọrun alaanu ni Ọlọrun wa, ti yoo si da si ọrọ orileede yii ati pe ọpẹ lo maa gbẹyin.

Ninu adura Biṣọọbu Fape lo ti gbadura fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu pe ki Ọlọrun tubọ fun lẹmi ọgbọn ti yoo fi tubọ dari orileede yii si ọna ti yoo gba mu irọrun wa.


No comments:

Post a Comment

Pages