Ṣe lọpọ awọn araalu ti wọn wa nibẹ bẹrẹ ṣadura nla fun Ayeyẹmi nipasẹ oriire nla ti wọn sọ pe o mu bawọn niluu naa.
Gẹgẹ bi iwadii taa ṣe ile itura ọhun to jẹ alaja mẹra lo ni ibusun aadọta le nigba, bẹẹ lo tun jẹ pe ibi igbafẹ to gba ẹgbẹrun meji, bakan tẹnu kọ, tẹgan kọ, ibudo ti mọto yoo maa duro si ni yoo maa gba ẹgbẹrun kan mọto lẹẹkan soso.
Ninu ọrọ oludasilẹ ile itura tuntun ọhun,Olufẹmi Ayeyẹmi, o kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun lori bo ṣe mu erongba ọkan ẹ ṣẹ lori ootẹli naa.
O sọ pe idasilẹ ootẹli ọhun ni ko le dọgba pẹlu tawọn agbaye ati pe yoo tun jẹ anfaani nla lati jẹ ki ọrọ aje tun lọ soke.
Ayeyẹmi waa dupẹ lọwọ Olu Ọbada oko, Ọba Olufẹmi Abiọdun atawọn oloye ẹ fun atilẹyin nla ti wọn ṣe lati le jẹ ki irufẹ ootẹli yii waye lagbegbe wọn.
Nigba to n sọ nipa kikọ ootẹli naa, o sọ pe ọ gbawọn to ọdun meje kawọn to pari ẹ, nitori ṣe lawọn ṣagbekalẹ ẹ lọna ti yoo ba ti agbaye mu.
O lo gba oun laaye lati rin irinajo kaakiri oke oke lati wo bi ootẹli wọn ṣe ri lọhun, to si jẹ pe gbogbo ohun elo to wa nibẹ gbankọgbi ni.
Ninu ọrọ Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludasilẹ ọna abayọ, iyẹn The Alternative, lo ti gboṣuba fun Ayeyẹmi pẹlu iṣẹ akanṣe eyi to sọ pe yoo tubọ mu idagbasoke ba ọrọ aje ipinlẹ Ogun.
O sọ pe nnkan ti Ayeyẹmi ṣe yii jẹ ohun iwuri lati pe awọn ọdọ yooku nija lati fi tiẹ ṣe awokọṣe rere.
Ṣowunmi wa rọ Gomina Dapọ Abiọdun lati ran awọn ara agbegbe naa lọwọ nipasẹ atunṣe ọna.
Nigba toun naa sọrọ, olugbanilamọran agba fọrọ ilera fun Gomina Ogun, Dokita Kehinde Ọlọlade, o kan saara si Ayeyẹmi fun ootẹli tuntun to kọ naa. O rọ awọn eeyan pataki lawujọ lati fi ti ọkunrin ṣawokọṣe.
Ọpọ awọn to wa nibẹ naa ni wọn sọrọ iwuri lọjọ naa ti wọn si ṣadura nla fun un pẹlu.
Pabanbari ẹ ni ti Alaaji Wasiu Ayinde, K1, to forin dabira lọjọ naa..
No comments:
Post a Comment