Sẹnetọ Gbenga Daniel pariwo; Ẹyin ọba alaye, ẹ gba mi lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe di awọn iṣẹ akanṣe mi lọwọ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 30 November 2025

Sẹnetọ Gbenga Daniel pariwo; Ẹyin ọba alaye, ẹ gba mi lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe di awọn iṣẹ akanṣe mi lọwọ.



Sẹnetọ Gbenga Daniel, to n ṣoju agbegbe ẹkun Ogun East, nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti rọ awọn ọba alaye atawọn agbaagba niluu lati parọwa si Gomina Dapọ Abiọdun, ko jawọ ninu dida awọn iṣẹ akanṣe to n ṣe duro mọ,nitori ẹtanu oṣelu.

Ilu Ijẹbu igbo nijọba ibilẹ Ijẹbu North lo ti sọrọ ọhun lakooko to ṣabẹwo agbeyẹwo ibi to ba nnkan de eyi ti wọn pe ni BAT/OGD.

O sọ pe ọpọ awọn iṣẹ akanṣe to jẹ tijọba apapọ to n ṣagbekalẹ ẹ fun itẹwọgba nijọba ipinlẹ Ogun da a duro ti wọn ko jẹ kawọn agbaṣeṣe raye ṣiṣẹ nibẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, lara awọn iṣẹ akanṣe ọhun to mẹnuba ti iṣẹ ti n lọ lọwọ ko to di pe wọn da a duro ni Itarin ati ọna ọsibitu jẹnẹra to wa nijọba ibilẹ Ijẹbu North.

O sọ pe kawọn ọba alaye atawọn agba oṣelu tete da si kawọn iṣẹ akanṣe naa le tete bẹrẹ pada.

Daniel ṣalaye pe awọn iṣẹ akanṣe ijọba apapọ to  n tọpasẹ gẹgẹ bi ipo oun ni alaga ijọba ibilẹ ti paṣẹ pe ki wọn daa duro, labẹ aṣẹ jinnijinni ti wọn da bo o.

O fikun ọrọ ẹ pe " Ẹ jẹ ki n sọ kin ni kan fun yin, to ba fi le di inu oṣu kejila ọdun, ti wọn ko ba gbẹsẹ kuro lori dida iṣẹ duro, owo ti wọn na sori ọna ijọba apapọ yoo kuna, ṣe ni wọn yoo da owo pada sinu apo iṣuna to ti jade wa.

" Iṣẹ awa ta a wa nile igbimọ aṣofin agba ni ki a tọpaṣẹ iṣẹ akanṣe, ki a si gbe le ẹka ijọba apapọ ti yoo ṣiṣẹ lee lori,kaka ki ijọba ipinlẹ Ogun gboriyin fun wa, ṣe ni wọn n ba akitiyan wa jẹ"

O ni gbogbo ero kan wọn ni pe awọn agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ ọhun jẹ ti OGD, nitori ẹ ni wọn ṣe n ba gbobo nnkan to ba nii ṣe pẹlu oun jẹ.

Aṣofin naa tun wa rọ awọn ọba alaye lẹẹkan si lati ba Gomina sọrọ nitori ifẹ awọn araalu.

Bakan naa lo tun sọ pe lati bi ọdun meji sẹyin ni ẹgbẹ BATOGD ti n tẹsiwaju lati jẹ kawọn araalu fatilẹyin wọn han si ipadabọ Asiwaju Bọla Ahmed lẹẹkeji gẹgẹ bi aarẹ orileede yii.

Bẹẹ lo tun lo akoko  ọhun lati gboriyin fun Aarẹ Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ lori bi wọn ṣe tete da si wahala to n waye ninu ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun.

O lawọn nigbagbọ lori iwadii ti wọn fẹẹ ṣe pẹlu idaniloju pe okodoro yoo farahan.

No comments:

Post a Comment

Pages