Aini ibẹru Ọlọrun lo n ṣokunfa ijinigbe ati ipanyan lakooko yii- Al-Khaleefah Ọlọrunṣẹyẹ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 29 November 2025

Aini ibẹru Ọlọrun lo n ṣokunfa ijinigbe ati ipanyan lakooko yii- Al-Khaleefah Ọlọrunṣẹyẹ.



Fadilat Sheikh Al-Khaleefah Abdul Quadri Ishọla Ọlọrunṣẹyẹ, to jẹ oludasilẹ ileewe JAMHYAT NUUR SOMODANY AL-ISLAMY FOUNDATION, iyẹn ile-ẹkọ ti wọn ti n kọ ọmọ lẹsin islam, to wa lagbegbe Ọbantoko, niluu Abẹokuta ti sọ pe aini ibẹru Ọlọrun lọkan lo jẹ ki iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran gbilẹ lakooko yii.

O sọrọ yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ayẹyẹ ọjọọbi Anọbi, ta a mọ si Maolid Nabiyy ati fi fawọn eeyan lami ẹyẹ, to waye laipẹ yii ninu ọgba ileewe girama Nawarudeen,Ọbantoko niluu Abẹokuta.

O  sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ bi ẹsun ijinigbe yii ko ṣe fọkan awọn araalu balẹ, to si n jẹ ki eto aabo mẹhẹ lorileede yii. O  ni Ọlọrun gan an sọrọ ninu kuraani lori ọna abayọ to le dẹkun ẹ.

Al-Khaleefah Ọlọrunṣẹyẹ sọ pe nnkan ti sura naa ṣe lalaye ni bi Ọlọrun ṣe ṣe adehun lori awọn to ba nigbagbọ lati fi wọn ṣe arole sorilẹ.
O ni ibẹru Ọlọrun ṣe koko, to ba ti wa eto aabo wa ko ni mẹhẹ mọ, O ni bẹẹ ni ti ẹsin ba tun rinlẹ, o di dandan ki gbogbo wahala yii di ohun itan.

Nigba to n sọrọ nipa ayẹyẹ ọjọọbi Maold Nabiyy ti wọn ṣe lọjọ naa, Ọlọrunṣẹyẹ sọ pe nnkan ti Ọlọrun ọba pa laṣẹ lati maa ṣe ni.

O ni " Ọlọrun ọba ni ki a ma ṣe aṣalatu,awọn kan tiẹ sọ pe ọjọọbi Anọbi ta a n ṣe yii Anọbi gan an funra ẹ ko ṣe e.Wọn ni ko lẹtọọ.

"Ṣugbọn ko ri bẹẹ,Anọbi n ṣe ọjọọbi, amọ ki i dana tabi ṣe ounjẹ, ko pero jọ, idi ti ko fi n ṣe e ni pe akoko naa nnkan le fun un, o n jagun ẹsin lọwọ nigba naa.
"Amọ ọna to maa n gba ṣe ni pe o maa n gbawẹ lẹẹmeji lọsẹ iyẹn ọjọ Aje ati Ọjọbọ.Ọjọ Aje yẹn ni wọn bii amọ Ọjọbọ lo ni wọn maa n gbe adura lọ sọdọ Ọlọrun"

Bẹẹ.ni agna oniwaasi naa tun sọ diẹ nipa itan igbesi aye ẹ ati pe Baba to bi oun lọmọ lo fi ẹsin islam le oun lọwọ, nitori oun ni ẹni to kọkọ aṣọ wọridi ni Abẹokuta
Agba Aafaa, akọmọ ni keu, onitẹsuba ati oniwaasi lo pe baba ẹ nigba to wa laye.

O nigba toun ti lọ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama ni Abẹokuta ni baba oun ti tunran oun lati tun fi kọ imọ si nipa ẹsin islam, eyi to gbe de iIlọrin ati Ẹdẹ, ko to di pe oun tun lọ kẹkọọ si lawọn ileewe giga nipa islam.

No comments:

Post a Comment

Pages