Beeyan ba jori ahun ko si ki omi maa bọ loju ẹ lakooko ti mama agbalagba kan to ti le lẹni aadọrun ọdun, Abibat Abatan, lati Ikorodu, to jẹ ẹbun amu nnkan tutu, iyẹn firigi nla nibi ayẹyẹ ayajọ Owuyẹ ti agba sọrọsọrọ nni, Oloye Makinde Fasunle, tọpọ mọ si Ọmọ Aye tabi Sẹnetọ ṣe niluu Abẹokuta.
Gẹgẹ bi wọn ṣe pe nọmba mama naa nibi tẹtẹ oriire fun ẹbun firiji naa lo fo dide siwaju awọn to n dari eto ọhun.
Ṣe ni mama naa n yi nilẹẹlẹ to pariwo pe ọpẹlọpẹ Fasunle lara oun, nitori pe oun ko lọmọ kankan laye, iṣoro airiran lo gbe ohun de ọdọ ẹ nigba naa lọhun, ti wọn fi ṣiṣẹ abẹ foun.
Koda mama naa sọ pe oun ya owo mọto wa sibi eto naa, ti Fasunle foun ni ankara ti mu lọfẹẹ, ọrọ ti Abibat n sọ yii di pe o mu oriire nla ba a.
Loju ẹsẹ lawọn to lamilaka lawujọ yii fi bẹrẹ si ni n fun lẹbun owo, ilẹ ati ile, koda wọn ni yoo maa gba owo loṣooṣu.
Gbogbo bi eto yii ṣe n lọ lo n mu ori awọn eeyan wu, ti wọn kọ mgba ti omi fi n bọ loju wọn koda Ifankaleluya, Makinde Fasunle atawọn sọrọsọrọ mii ii kọ mọgba ti omi fi n bọ loju wọn.
Nigba ti Fasunle jẹri si ọrọ mama naa, o sọ pe lati bi ọdun kan sẹyin ni Mama naa ti maa n wa lati Ikorodu pe oun fẹ iranlọwọ lori oju to n yọ oun lẹnu.
O ni ko si pẹ tawọn eeyan dide iranlọwọ fun un ti wọn fi ṣiṣẹ abẹ fun un. Latigba naa ni ko ti fi oun silẹ.
Ohun to tun jẹ iṣẹlẹ iyanu mii nibi ayẹyẹ Owuyẹ ọhun to waye ni ti Pasitọ ijọ Ridiimu to jẹ ẹbun ile lọfẹẹ.
Akinlemi Bọla John Kẹhinde lorukọ pasitọ naa, gẹgẹ bo ṣe wi o ni ko to to akoko yii loun ti n ri ninu iran pe Ọlọrun fẹẹ kọle foun lọfẹẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni latigba toun ti ra tikẹẹti loun ti n ṣe iṣọ oru pe ki Ọlọrun mu ileri ẹ ṣẹ.
Bakan naa koun to kuro nile lọjọ naa loun tun ti sọ pẹlu igbagbọ pe oun yoo jẹ ẹbun ile naa amọ ti Ọlọrun waa fi aṣẹ si.
Bakan naa lọpọ awọn eeyan to wa sibi eto ọhun tun jẹ ẹbun loriṣiriṣii.
No comments:
Post a Comment