Larfage tun ṣe bẹbẹ fawọn araalu ni Ewekoro.Ile ẹkọ alakọọbẹrẹ igbalode tuntun ni wọn kọ fun wọn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 27 November 2025

Larfage tun ṣe bẹbẹ fawọn araalu ni Ewekoro.Ile ẹkọ alakọọbẹrẹ igbalode tuntun ni wọn kọ fun wọn

Ṣe ni inu awọn araalu nijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ Ogun bẹrẹ si nii dun ṣẹkẹ, nigba ti ileeṣẹ simẹnti Larfage mu idunnu ba wọn nipaṣẹ ileewe alakọọbẹrẹ igbalode ti wọn kọ fun wọn, ti wọn ṣi ṣii laipẹ yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileewe alakọọbẹrẹ kan ti wọn pe ni Christian Pelamourges Memorial Baptist Day Nursery and Primary School, to wa ni Agbesi, Ewekoro ni wọn ṣe atunkọ ẹ.

Iwadii fi ye wa pe lati bi ọdun meloo kan  sẹyin nileewe ọhun ko ti wa nipo to dara, to si n ko abuku nla bawọn eeyan agbegbe ti wọn ran ọmọ lọ kẹkọọ nibẹ to fi mọ awọn olukọ wọn pẹlu.

Gbogbo akitiyan ni wọn sọ pe wọn ti sa lati le jẹ atunṣe ba ile ẹkọ ọhun to si jẹ pe pabo ni gbogbo rẹ ja si.

Ko to waa di pe ileeṣẹ Larfage gbe igbesẹ lati ṣatunkọ ileewe ọhun lọna igbalode ti yoo boju mu, ti wọn si sọọ di ile ọba to jọ ẹwa lo bu si.

Atẹjade kan ti akoso agba lẹka eto ikansira-ẹni nileeṣẹ naa, Arabinrin Ginikanwa Frank-Durugbor fi sita, o ni ki eto ẹkọ le rọrun fun akẹkọọ ati olukọ ni wọn gba ṣatunkọ ile-ẹkọ naa.

Frank-Durugbor ni awọn kọ kilaasi tuntun,wọn tun ṣe orule to jọju, to fi mọ ọfiisi awọn oṣiṣẹ ati kikọ ṣalanga igbalode ati omi ẹrọ igbalode, fun irọrun awọn eeyan.

Bakan naa lo ni yara ikawe ati, aga ati tabili tuntun, to fi mọ gbogbo ohun ti ile-ẹkọ, paapaa akẹkọọ ati olukọ nilo lati mu ki iṣẹ rọrun ni wọn ṣe sibẹ fun wọn.

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade naa, alakoso agba ileeṣẹ naa, Lolu Alade-Akinyẹmi sọ pe lara awọn agbekalẹ ileeṣẹ naa lati gbajumọ ọrọ eto ẹkọ ati awọn ohun ti yoo mu idagbasoke ba agbegbe ati igberiko.
Ni ileeṣẹ Lafarge Africa, a nigbagbọ pe eto ẹkọ to ye kooro jẹ ohun elo lati fi ṣe igbarugẹ fun ọjọ ọla awọn ọmọde.

" Nipasẹ irufẹ awọn iṣẹ akanṣe bii ile-ẹkọ Christian Pelamourges Memorial Baptist Day Nursery and Primary School, to wa ni Agbesi, kii ṣe pe a n ṣagbelarugẹ fun ile kikọ nikan, bi ko ṣe pe a tun n ko ipa nigbesi aye awọn ọkan tuntun ti yoo gbe orileede yii soke nipa ẹkọ gidi,” Alade Akinyẹmi sọ bẹẹ.

“Ohun ti a ṣe yii lo ṣafihan ifarajin wa nipa igbelarugẹ si iṣẹ ilu, paapaa agbegbe to gba wa tọwọ-tẹsẹ, lati rii daju pe a ko ya ọmọ kankan sọtọ.”

Nigba toun naa n sọrọ, Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu sọ pe iṣẹ akanṣe naa ṣe deedee, to si lọ ni ibamu pẹlu idagbasoke eto ẹkọ lagbaye.

Bẹẹ lo gbe oṣuba kare fun awọn alakoso naa, lori ọna ti wọn n gba ṣe iranwọ fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, to si ni o lọ ni ibamu pẹlu afojusun ijọba labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun.





No comments:

Post a Comment

Pages