Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣi ni Sẹnetọ Gbenga Daniel- Akọwe ẹgbẹ lapapọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 19 November 2025

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣi ni Sẹnetọ Gbenga Daniel- Akọwe ẹgbẹ lapapọ



 Okodoro ti farahan bayii pe titi di akoko yii ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC,ipinlẹ Ogun ṣi ni Sẹnetọ Gbenga Daniel ati pe ko si igba kan ti ẹgbẹ naa lapapọ fọwọ si idaduro ẹ ninu ẹgbẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Sẹnetọ  Surajudeen Ajibọla Baṣiru, akọwe ẹgbẹ APC lapapọ fi sita lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii lo ti sọ pe ahesọ patapata ni iroyin tawọn kan gbe jade pe awọn ti fọwọ si idaduro aṣofin to n ṣoju ẹkun Ogun East nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja.

Ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin, ni atẹjade kan fọn si igboro latọdọ ijọba ipinlẹ Ogun pe ẹgbẹ lapapọ ti fọwọ si yiyọ Gbenga Daniel kuro ninu ẹgbẹ latari ẹsun agabagebe ti wọn fi kan an.

Loju ẹsẹ ni Steeve Oliyide, akọwe iroyin Aṣofin Daniel, ti tako iroyin naa gẹgẹ bi eyi ti ko fẹsẹrinlẹ,ti ko si ẹri gidi ti wọn fi le gbe e lẹsẹ.

Ṣugbọn ni bayii, akọwe ẹgbẹ ti wa ṣoju abẹ niko pe ko tii si nnkan to yẹ Daniel lẹsẹ ninu ẹgbẹ wọn.

O sọ pe igbimọ ẹgbẹ ko tii jokoo lati ṣe iwadii le e lori gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ fun wọn.

Nitori idi eyi, o ni titi digba tawọn yoo fi pari wọn ọmọ ẹgbẹ APC ipinlẹ Ogun ni Sẹnetọ Daniẹl.


No comments:

Post a Comment

Pages