Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, akọwe fẹgbẹ oṣelu ADC lorileede yii ti sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ pe gbogbo opo iṣejọba orileede yii lo ti wo lulẹ patapata, eyi to si n ba ninu jẹ pupọ.
O sọrọ yii lakooko tawọn ogunlọgọ awọn eeyan wa pade ẹ ni aafin Ọrangun tiluu Ila, Ọba Wahab Kayọde Adedeji Oyedọtun. O sọ pe awọn bii eto aabo, imayedẹrun,eto ẹkọ ati ọrọ aje lo ti mẹhẹ patapata.
Ẹni to ti figba kan jẹ Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, ṣalaye pe nigba ti ebi ba n paayan ti wọn jẹ irora,ti a ko le nawọ aanu si wọn, ti a ko le jẹwọ Ọmọluabi.
O ni o da oun loju pe inu Awolọwọ to jẹ babanla nidii oṣelu ko le dun, lori ipo ti orileede Naijiria wa.
Arẹgbẹṣọla tun sọ fawọn to wa nibi ibẹrẹ abẹwo to bẹrẹ sawọn agbegbe ẹkun mẹsan an to wa nipinlẹ naa pe lati nnkan bi ọdun meji sẹyin tawọn to wa nipo ti n ṣejọba, ni wọn ti kuna lawọn opo to ṣe pataki si ọrọ ọmọniyan. O nidii re
tawọn ọmọ orileede yii ko ṣe ṣe itẹwọgba awọn adari to wa nipo yii.
O sọ pe pataki abẹwo oun kaakiri awọn ẹkun ati agbegbe ipinlẹ Ọṣun lati ta wọn ji ati lati sọ nipa ẹgbẹ oṣelu ADC, ti yoo mu ayipada rere olori ati iṣejọba tuntun ba orileede Naijiria. Ni eyi ti yoo din iṣẹ oun iya awọn araalu ku.
Lara agbegbe ti wọn ṣabewo de lọjọ naa ni Ifẹoluwa, Ila ati Boluwaduro.
No comments:
Post a Comment