O sọrọ yii lakooko nigba to n sọkalẹ ni papakọ ofurufu naa ni Ipẹru, eyi to gbe e wa lati Abuja.
Ṣowunmi sọ pe idunnu nla lo jẹ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lapapọ fun aṣeyọri nla lori papakọ ofurufu ọhun,eyi to sọ pe yoo tun mu ki ọrọ aje ipinlẹ Ogun tun gun rege sii.
O gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun lori bo ṣe pari iṣẹ ọhun ati Ọtunba Gbenga Daniel to bẹrẹ ẹ.
O ṣakiyesi pe pẹlu papakọ ofurufu yii, ohun iwuri lo jẹ lagbo ọrọ aje lagbaaye ati pe olokoowo to ba sọ pe oun ko le daṣẹ silẹ ti padannu nla.
Ọkunrin naa tun fikun ọrọ ẹ pe gbogbo nnkan to wa lọkan oun lakooko ti Ọtunba bẹrẹ ẹ pe igbawo ni yoo to pari laimọ pe akoko yii ni imuṣẹ naa di mimuṣẹ.
Ṣowunmi ni ẹkọ kan toun ri kọ nibẹ ni pe ti anfaani kan ba fẹẹ sọnu, ki eeyan ma sọ ireti nu, nitori o le di mimuṣẹ lọna ara. O ni papakọ ofurufu Ipẹru yii waa di ọkan pataki ti ko lafiiwe.
No comments:
Post a Comment