Ọmọ ale ni yoo tako idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu- Sẹnetọ Gbenga Daniel - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 12 October 2025

Ọmọ ale ni yoo tako idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu- Sẹnetọ Gbenga Daniel


Ṣẹnetọ Gbenga Daniel, to n ṣoju ẹkun Ogun East, nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti sọ pe ọmọ ale Ijẹbu nikan ni ko nii jẹ ki idasilẹ ipinlẹ naa waye.

O sọrọ yii nibi abẹwo idupẹ to ṣe de ijọba ibilẹ Ijẹbu East, to waye lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii.

Gbenga Daniel sọ pe akoko ti to ki gbogbo wọn jọ pawọpọ fimọsọkan lati jẹ ki erongba naa di mimṣẹ.

O ṣalaye pe awọn nikan kọ ni wọn jọ gbe igbesẹ lati gba ipinlẹ tuntun ati pe ninu gbogbo awọn ti wọn jọ n du, ẹnkan kan ṣoṣo ni wọn yoo fun nilẹ Yoruba.

O fikun ọrọ ẹ pe oore ọfẹ kan ṣoṣo ti Ijẹbu n jẹ ni pe ninu gbogbo awọn to pinnu lati gba ipinlẹ tuntun Ijẹbu nikan ni wọn ti ṣeleri fun latọjọ pipẹ ọdun pipẹ.

O waa rọ awọn ọmọ ilu Ijẹbu lapapọ ki wọn ma ṣe jẹ ki anfaani yii ko fo wọn ru,ki ala ọjọ pipẹ le di mimuṣẹ.
 
Daniel tun sọ pe" Iya ti jẹ  wa ni Ijẹbu o, a o si ni gba ki ara iwaju wa dero ẹyin, ọna taa si le gba ni pe ki ẹ la eti yin sita, ki ẹ la oju yin silẹ

" Nigba kan ri Akilẹ Ijẹbu ni wọn pe wa, njẹ a ṣi n kilẹ bi, lakooko ti mo wa nipo gomina, a ri ọgbọn da si papakọ ofurufu, a gbe si Rẹmọ, a gbe Sea Port, wa si Ijẹbu, bẹẹ la gbe ileifọpo Dangte wa si ijẹbu bakan naa'   

O ni iyalẹnu lo jẹ pe nigba toun gbe ipo silẹ, loun gbọ pe wọn gbe ile ifọpo Dangote lọ si Eko

Nnkan nla lo sọ pe Ijẹbu sọnu, o waa rọ wọn pe ki wọn ma jẹ kiru anfaani bẹẹ tun sọ wọn nu nipa idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu tuntun yii.

Bẹẹ lo tun lo akoko naa lati rọ Gomina Dapọ Abiọdun lati ba wọn yanju ibudọkọ oju omi iyẹn Sea Port.

No comments:

Post a Comment

Pages