Ohun ta a gbọ ni pe o ti le ni ọdun mẹtadinlogoji ti ipo yii ti ṣofo niluu naa.Ko to wa di pe wọn fi ọmọ oye jẹ.
Ọṣọrun ni wọn sọ pe o jẹ ọkan lara oye afọbajẹ niluu Iṣhaga Orile. Ninu ọrọ Oloye tuntun naa lẹyin ti Ọba ilu naa, Ọba Joseph Ọladele Olusọji Tella, jawe oye le lori lo ti sọ pe oye Ọṣọrun ki i ṣe ayọjuran foun rara bi kp ṣe oye awọn baba nla mi.
Ọdun 1988 lo sọ pe ọkan lara awọn ẹgbọn oun ti joye naa gbẹyin, iyẹn lati ọdun 1958 to ti wa nibẹ.
Ọdunaro fikun ọrọ ẹ pe oye tuntun toun jẹ yii yoo jẹ ki oun tubọ sunmọ awọn araalu, ki ajọṣepọ to dnmọran tubọ fi le wa laarin wọn.
Bẹẹ lo ni yoo tubọ jẹ ki oun maa kopa to jọju ninu aṣa ati iṣe ilu naa paapaa lakooko ti wọn ba fẹẹ yan ọba tuntun niluu Ishaga Orile.
O waa pari ọrọ ẹ pe oun yoo lo gbogbo iriri oun toun ti ni lati fi mu idagbasoke ba ilu ọhun.
No comments:
Post a Comment