Ọpẹ ooo! Rasaq Shofowora di alaga fẹgbẹ oṣelu NNPP Ogun East - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 4 October 2025

Ọpẹ ooo! Rasaq Shofowora di alaga fẹgbẹ oṣelu NNPP Ogun East



Lọsẹ taa lo tan yii ni ẹgbẹ oṣelu NNPP ipinlẹ Ogun kede kọmureedi Rasaq Ṣẹgun Shofowora, gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa fẹkun Ogun East nipinlẹ Ogun.

Ọkunrin yii lo jade dupo fun ipo aṣoju-ṣofin fun ẹkun Rẹmọ  labẹ ẹgbẹ oṣelu nibi ibo to waye ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin.
Nibi ayẹyẹ ṣiṣi ọfiisi ẹgbẹ tuntun ọhun to waye ni Odogbolu ni wọn ti kede Shofowora fun ipo tuntun naa pẹlu itẹwọgba gbogbo ọmọ ẹgbẹ.

Ni bayii alaga tuntun ọhun tọpọ tun mọ si RSS, ti waa fi ẹmi imoore han si awọn olori ẹgbẹ naa lapapọ.

Ninu iwe idupẹ to fi sita ọhun lo ti dupẹ lọwọ Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo fun imọriri ati atilẹyin ẹ lori ẹgbẹ NNPP ipinlẹ Ogun ati lorileede yii lapapọ, o ṣapejuwe ẹ gẹgẹ aṣaaju to ṣe fi ṣe awokọṣe rere.

Bakan  naa lo tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn oloye ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun bẹrẹ lati ori alaga wọn Agbẹjọro Fẹmi Aina atawọn igbimọ ẹ ti wọn jọ n ṣakoso ẹgbẹ naa fun igbagbọ ti wọn ni ninu oun pẹlu ileri pe oun yoo sa agbara oun lati rii pe ijakulẹ ko deba NNPP Ogun East lakooko toun.

No comments:

Post a Comment

Pages