O tan:Alaga APC tẹlẹ ni Enugu atawọn ọpọ eeyan darapọ mọ ADC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 23 October 2025

O tan:Alaga APC tẹlẹ ni Enugu atawọn ọpọ eeyan darapọ mọ ADC



A fi bii awọro lọrọ naa jẹ nipinlẹ Enugu, nigba ti alaga fẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ, Ọgbẹni A C Udeh ati olori awọn obinrin,Lolo Nwakwo, to fi mọ awọn alaga wọn nijọba ibilẹ mẹwaa atawọn ọpọ eeyan mii in fẹgbẹ naa silẹ, ti wọn si darapọ mọ ADC.

Nibi ipade ẹgbẹ oṣelu ADC, to waye ninu ọsẹ yii ni wọn ti gba awọn eeyan ọhun sinu ẹgbẹ pẹlu idunnu ati ayọ ni ọfiisi wọn to wa ni Enugu.

Igbesẹ yii waye nitori bi Gomina ipinlẹ ọhun, Peter Mbah, ṣe kuro ninu ẹgbẹ PDP bọ si APC, eyi ti wọn sọ pe o mu rukerudo bawọn ninu ẹgbẹ APC.

Ohun ta a gbọ ni pe bi Mbah ṣe bọ sinu APC, ko tẹ ọpọ ọmọ ẹgbẹ lọrun, to si jẹ ki wọn pin yẹlẹyẹlẹ, eyi lo si fa tawọn eeyan naa fi darapọ mọ ADC.

Ni bayii, awọn to ṣẹṣẹ darapọ mọ ADC, nipinlẹ Enugu, ti waa ṣeleri atilẹyin nla pẹlu lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn to wa nibẹ lati le jẹ ki ẹgbẹ oṣelu naa rọwọ mu, ninu gbogbo ibo to n bọ lọna.

No comments:

Post a Comment

Pages