Afeez Oyètòrò, Tai Arógunmátìdí fẹ́ẹ́ dáwọn onítíátà ANTP l'ẹ́kọ́ọ̀ níbi àpérò ẹlẹ́ẹ̀kejì irú ẹ̀. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 22 October 2025

Afeez Oyètòrò, Tai Arógunmátìdí fẹ́ẹ́ dáwọn onítíátà ANTP l'ẹ́kọ́ọ̀ níbi àpérò ẹlẹ́ẹ̀kejì irú ẹ̀.


Gbogbo eto lo ti pari fun eto ayẹyẹ apero ti ẹgbẹ oṣere tiata ANTP maa n ṣe, eyi ti ẹlẹẹkeji iru ẹ yoo waye ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọmọọba Olufẹmi Adejọnwo, alaga igbimọ to ṣeto ọhun fi sita lo ti ṣalaye pe gbọngan NUJ, to wa ninu ọgba ileeṣẹ tẹlifiṣan BCOS, ni eto ọhun yoo ti waye ni dede aago mejila ọsan.
 
Lara eto ti wọn ni lọjọ naa ni idanilẹkọ nibi ti gbajumọ oṣere tiata nni, to tun jẹ olori ẹka ti wọn ti n kọ oṣere nileewe giga yunfasiti tipinlẹ Eko, iyẹn Dokita Afeez Oyetoro tọpọ mọ si Simply Saka.

Awọn yooku tun ni Aarẹ Akọgun Tai Arogunmatidi, ti wọn jẹ agba ọjẹ ninu ki wọn ya sinima ati Ọjọgbọn A B S Akande lati ilẹ Amẹrika.

Alaga igbimọ ayẹyẹ ọhun tun sọ pe agbekalẹ idanilẹkọ ọhun lara eto ti Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Dokita Rasak Ọyadiran, tọpọ mọ si Baroka fi le lẹ lati mu itẹṣiwaju ba iṣẹ ti wọn yan laayo.

Lara awọn agba oṣere ti wọn yoo wa ni ikalẹ ni Oloye Lere Paimọ, tọpọ mọ si Ẹda, Oloye Yẹmi Ẹlẹbuibọn, Ambasedọ Yẹmi Farounbi, Alagba Oyewọle Olowomojuọrẹ, Baba Gebu atawọn agba oṣere yooku.

Nigba ti Dokita Rasak Ọyadiran yoo jẹ olugbalejo pataki, tawọn oṣere ANTP lawọn ipinlẹ yoo wa nijokoo lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages