Àràbà Awo ilẹ Oṣogbo. Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ti ṣalaye ewu to wa fun iyawo ile ti ko jẹ oloootọ si ọkọ rẹ.
Lọjọ Tọsidee ọsẹ yii lo sọrọ naa lasiko to gba ajọ Ọmọ Yoruba Atata Socio-cultural Initiative, ỌYÀSI, lalejo nile ẹ, to wa ni Opopona Ẹlẹbuibọn, niluu Oṣogbo, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.
Abẹwo ọhun lo jẹ ara imurasilẹ de Ayajọ Ọ̀ṣọ́ Orí, ti wọn tun n pe ni Ayajọ Fila ati Gele ẹlẹekeji, eyi ti yoo waye lọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu Kejila, ọdun 2025 yii lẹyin ti wọn ti kọ ṣe ọkan lọdun 2024 ni papa iṣere Lekan Salami, lAdamasingba, n'Ibadan, eyi si to akọkọ iru ẹ lagbaaye.
Ẹlẹbuìibọn, ẹni ti gbogbo eeyan mọ nilẹ yii ati kaakiri agbaye ninu imọ ijinlẹ nipa ifa dida ati iṣẹṣẹ Yoruba, ṣalaye pe ki awọn Oyinbo too gbe imọ sayẹnsi de lawọn Yoruba ti ni aṣa to pe, ti awọn paapaa si ni ọna ti wọn n gba da ọmọ ale mọ yatọ si ọmọ ọkọ lailọ siwaju dokita lọọ ṣayẹwo ẹjẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ,"Ọṣọ ara ṣe pataki pupọ fun ọkunrin ati obinrin nilẹ Yoruba, paapaa, aṣa fila dide ati gele wiwe sori gẹgẹ bii nnkan ti ẹyin Ọmọ Yoruba Atata gbe lọwọ yii.
"Yoruba ti ni aṣa tiwọn to pe pẹrẹpẹrẹ, ki i ṣe pe awọn Oyinbo atọhunrinwa ni wọn ṣẹṣẹ waa kọ wa ni oge ṣiṣe.
"Ọrọ fila ati gele tẹ ẹ waa gbe dani yii, o ṣe pataki pupọ, paapaa fun awọn ọmọde aye ode oni ti wọn ko mọ ọtun yatọ si osi.
"Loootọ la n lo fila lati gbẹbi fun obinrin to ba pẹ lori ikunlẹ, ṣugbọn ki i ṣe gbogbo eeyan lo le ṣiṣẹ fun, obinrin to ba jẹ oloootọ si ọkọ rẹ nikan lo le ṣiṣẹ fun.ara nnkan ti awa n lo gẹgẹ bii DNA niyẹn.
"Obìnrin fi gbọdọ jẹ oloootọ si ọkọ rẹ. Ṣe ẹ mọ pe Yoruba ki i ṣe ayẹwo laye atijọ lati mọ ọkunrin ti obinrin bimọ fun, ara ọna ti wọn n gba ṣayẹwo ẹjẹ lati mọ baba ti obinrin bimọ fun laye atijọ niyẹn."
O waa gboṣuba fun ajọ Ọmọ Yoruba Atata Socio-cultural Initiative, fun akitiyan wọn lori igbelarugẹ aṣa ati iṣe Yoruba, paapaa, nipa ayajọ fila ati gele lagbaaye ti wọn gbe lọwọ 
Bakan naa lo ṣeleri atilẹyin rẹ fun ajọ wọn lori eto ọlọdọọdun naa, eyi ti wọn nireti pe ajọ agbaye ta a mọ sí UNESCO yoo tẹwọ gba laipẹ, ti yoo sọ di ohun ti gbogbo agbaye n ṣe lorilẹ-ede gbogbo lọdọọdun.
Ṣaaju, nigba to n sọrọ lori pataki abẹwo wọn ọhun, ni alaga ajọ ỌYÀSI, Ọgbẹni Ọlawale Ajao, ti ṣalaye ni awọn Yoruba ṣe n lo fila ati gele fun oroṣiiriṣii iṣe iyanu.
Ajao, ẹni ti Ọgbẹni  Adeyẹmi Oloriire, Kọlawọle Ọlatunji, ati Yetunde Ọlalere, kọwọọrin pẹlu ẹ ninu abẹwo ọhun, waa kan saara si agba ọjẹ babalawo naa fun akitiyan rẹ nidii agbega aṣa Yoruba nigba gbogbo.
No comments:
Post a Comment