Eyi lawọn aṣeyọri nla ti ileeṣẹ Lafarge tun ṣe laipẹ yii - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 24 October 2025

Eyi lawọn aṣeyọri nla ti ileeṣẹ Lafarge tun ṣe laipẹ yii

Pẹlu idunnu ati ayọ nileeeṣẹ to n ṣe simẹnti lorileede yii iyẹn Lafarge Africa Plc fi kede awọn ere nla ti wọn ri lọdun yii, eyi
 to gbọgbọrọ ju ọdun to kọja lọ.

 Ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin ileeṣẹ naa, Arabinrin Ginikanwa Frank-Durugbor fi ranṣẹ, ida mẹtalelọgọta ni ere ti wọn jẹ fi le si ti ọdun to kọja.

O sọ pe N780.48 biliọnu naira ni owo to wọle sapo awọn laarin oṣu mẹsan ninu ọdun 2025, to si ni iwuri nla lo jẹ fun wọn nileeṣẹ naa.

O fikun ọrọ ẹ pe N 479.49 biliọnu naira ni owo ere ti awọn jẹ lọdun 2024, to si ni ti ọdun yii kọja bẹẹ.

Siwaju sii lati jẹ ko di mimọ pe ere ti awọn jẹ lẹyin ti awọn ti yọ owo ori fun ijọba le ni aadọta biliọnu N60.08 naira.
 
Bakan naa lo ni awọn aṣeyọri wọnyi ko ṣẹyin owo naira ti ko ṣe segesege, ati alekun lori iṣẹ ti wọn gbe jade.

Bakan naa, nigba to n sọrọ, Lolu Alade-Akinyẹmi, to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ Lafarge Africa, ṣalaye pe aṣeyọri saa kẹta ninu ọdun ṣafihan ikora-ẹni nijanu ninu owo ọja , ọja to ba igba mu, ati ṣiṣe awọn ohun itẹwọgba lawujọ.

O loo jẹ ohun iwuri lati tilẹkun saa kẹta ninu ọdun 2025 pẹlu aṣeyọri to jọju, nipa ere ida mẹtalelọgọta, to si fi da awọn loju pe awọn araalu n ṣamulo ọja ti wọn n gbe jade.

No comments:

Post a Comment

Pages