Bi nnkan ṣe n lọọ yii afaimọ ki wahala to n waye ninu ẹgbẹ OPC New Era, maa di ohun ti yoo fọ ẹgbẹ naa si wẹwẹ nitori bi ọkan lara agba ẹgbẹ naa, to tun jẹ alaga wọn nipinlẹ Eko, Alaaji Lateef Oṣodi ṣe fẹsun kan aarẹ ẹgbẹ naa Oloye Razak Arogundade Balogun, tọpọ mọ si Saddam pe ko fẹẹ fipo to wa silẹ, lẹyin to ti lo ọdun mẹjọ to wa ninu iwe ofin wọn pe.
Gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe wi, o ni nnkan to wa ninu iwe ofin lẹyin ti wọn da ẹgbẹ naa ni pe ki ẹni ti wọn ba yan sipo ba lo ọdun mẹrin-in, anfaani tun wa fun lati lo ọdun mẹrin-in mii-in.
Oṣodi tun tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe 'Ẹni to ba dalẹ, ki i dalẹ,nigba taa kọkọ bẹrẹ OPC latilẹ,Saddam ko si lara wa rara, ki i sọmọ ẹgbẹ wa rara.
"Nigba taa kuro lẹyin Faṣeun ti Gani Adams fẹsun kan Faṣeun pe o gba miliọnu lọna ọgbọn amọ ti baba sọ pe miliọnu mẹta loun gba.
"Eyi lo faa taa fi tẹle Gani Adams lọ, nigba to ya nija tun bẹ silẹ nigba tawọn Saddam atawọn tiẹ ti wọn pe ' 10 million Boys' ni wọn pe wọn.
Oṣodi lawọn eeyan yii fẹsun kan Gani Adams pe o gba owo nla, awọn si fẹẹ gba 10milion nibẹ, ti Gani si sọ pe miliọnu mẹfa loun gba, idi niyii tawọn fi tuka da OPC New Era silẹ.
Ohun to ni awọn si jọ fimọsọkan ninu iwe ofin ni pe aarẹ ko gbọdọ lo ju ọdun mẹjọ lọ amọ ti Saddam fẹẹ dalẹ wọn bayii.
O sọ pe kii ṣe pe nitori ki oun le di aarẹ loun ṣe pariwo, ẹnikẹni ni ẹgbẹ le ysn, amọ Saddam gbọdọ fipo naa silẹ, nitori akoko ẹ ti pe.
Bẹẹ lo tun sọ pe latigba toun ti pariwo sita lawọn kan ti n dunkoko mọ oun, toun si ti sọ fawọn ẹbi oun pe ti nnkan ba ṣẹlẹ si oun, nọmba foonu awọn ti wọn yoo tọpaṣẹ ẹ ree.
O waa ṣeleri pe ti Saddam ba yari lati gbe ipo aarẹ ẹgbẹ naa silẹ, oun ṣetan lati gbe lọ sile ẹjọ.
Ṣugbọn Oloye Rasak Arogundade Balogun ti sọ pe ko si wahala kankan ninu ẹgbẹ naa.
No comments:
Post a Comment