Aṣofin Gbenga Daniel, to n ṣoju Ogun East nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja ti sọ pe ifasẹyin nla ni yoo de ba erongba idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu bi wọn ko ba foun laaye lati dije gẹgẹ bi aṣoju wọn lẹẹkeji,ninu ibo ọdun 2027.
Lọjọ Aiku, Sannde, lo sọrọ yii lakooko abẹwo idupẹ to n ṣe kaakiri wọọdu to wa labẹ ẹkun East, eyi to waye niluu Igodẹ, lẹgbẹ Ogijo, nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinẹ Ogun.
O sọ pe nipinlẹ Ogun, agbegbe Ogun East lo ni agbegbe to pọju, mẹsan-an lo ni wọn ni, nigba ti Ogun Central ni mẹfa, nigba ti Ogun West ni mẹrin.
Aṣofin Daniel tun mẹnuba a pe ti erogba wọn ba di mimuṣẹ, a jẹ pẹ aṣofin agba mẹta ni wọn yoo maa ni niluu Abuja ati aṣoju-ṣofin mẹsan-an.
O tun ṣalaye siwaju pe " Ohun ta a n reti bayii ni igba ti aarẹ orileede yii yoo buwọ lu yala akoko taa n lo lọ yii tabi lẹyin ibo ti yoo waye lọdun 2027.
' Bi o ba jẹ lẹyin ibo ọdun 2027, ewu nla ni o, nitori bi ẹ ko ba dibo fun mi lẹẹkeji, yoo ṣoro lati jẹ ko di mimuṣẹ.
" Idi abajọ si ni pe ẹni to ba ṣẹṣẹ wọle yoo tun bẹrẹ igbesẹ ni latilẹ, nitori idi eyi ẹ ma jẹ ki anfaani idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu- Rẹmọ yii ko fo wa ru
Bakan naa lo tun mẹnuba igbesẹ tun ti wọn tun ṣẹṣẹ gbe lọjọ naa eyi ti wọn pe ni BAT/OGD, nibẹ lo ti sọ pe oun ko nii fọwọ osi juwe ile baba oun o. O ni kawọn araalu fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu laaye lati ṣe saa keji gẹgẹ bi aarẹ orileede yii.
O ṣalaye pe nigba ti Ọbasanjọ ṣejọba o lọdun mẹjọ,bẹẹ naa lo si yẹ ki Tinubu naa lo tiẹ pe, lẹyin to ba pari ẹ, ẹni to ba ku kawọn jọ jokoo sọ.
Bẹẹ lo sọ pe aimọye iṣẹ takuntakun ni Aarẹ Tinubu ti ṣe nitori idi eyi wọn gbọdọ tii lẹyin lati gẹgẹ bi ojulowo ọmọ Yoruba.
Bakan naa lo tun gboriyin fun Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lori bo ṣe pari papakọ ofurufu to wa ni Iliṣan, eyi tijọba ẹ bẹrẹ nigba to wa nipo gomina.
O waa rọ ọ lati jẹ ki iṣẹ tete bẹrẹ, ti yoo si jẹ ki ọrọ aje tun lọ soke lagbegbe naa.
Ninu ọrọ Ọba Onigodẹ, Ọba Jamiu Ọlalekan Sule- Ọnọṣipẹ, Onigodẹ tiluu Igodẹ, o dupẹ lọwọ Aṣofin Gbenga Daniel, lori awọn akitiyan ẹ lati mu idagbasoke ba ilu naa.
Lara awọn eto to tun waye lọjọ naa ni ṣiṣi ọja igbalode ti wọn kọ sllu ọhun bẹẹ ni wọn to ro awọn eeyan lagbara.
No comments:
Post a Comment