Nibi eto ọhun to waye niluu Abẹokuta lawọn musulumi ti pejọ nibi adura ti The Alterntive ọhun ṣagbekalẹ ẹ.
Ninu ọrọ Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, lo ti rọ awọn oloṣelu lati yẹra fun imọtara ẹni, ki wọn si lo awọn ohun alumọni ti wọn ti ri lorileede yii mu ayipada rere fawọn araalu.
O lawọn ṣagbekalẹ adura naa lati fi imọriri ati ipa ti Buhari ko lati mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba orileede wa lakooko to fi wa nipo aarẹ.
O ṣapejuwe Buhari gẹgẹ bi ẹni ti ko mu aye le, to si ko ara ẹ nijanu bẹẹ lo tun fi apẹẹrẹ rere silẹ nigba to fẹẹ kuro nijọba.
Ṣowunmi waa gba awọn aṣaaju oloṣelu nimọran lati fi awokọṣe rere silẹ, nitori awọn kan wa ti wọn n wo wọn.
O waa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere, ko si pa gbogbo aiṣedeede ẹ rẹ.
Imaamu agba ni Keesi, Sheik Akimu Ọlọrunniṣọla, lo ṣaaju adura nibẹ.
Mohammadu Robiu Adekọlu lo dawọn lẹkọọ. Ẹ o ranti pe ọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun yii ni Buhari dagbere faye niluu Oyinbo, lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.
No comments:
Post a Comment