Ẹgbẹ oṣelu ti ibo atundi to waye nipinlẹ Ogun ko ba tẹ lọrun le gba kootu lọ- Alaga IPAC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 21 August 2025

Ẹgbẹ oṣelu ti ibo atundi to waye nipinlẹ Ogun ko ba tẹ lọrun le gba kootu lọ- Alaga IPAC



Alaga fẹgbẹ apapọ oṣelu IPAC, nipinlẹ Ogun, Abayọmi Sanyaolu, ti rọ awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu ti wọn kopa nibi ibo atundi ile igbimọ aṣoju-ṣofin, to waye ni ẹkun Rẹmọ lọjọ Abamẹta,Satide, to waye,lati ma ṣe fi abajade esi ibo ọhun da wahala silẹ.

O ni ẹnikẹni ti ko ba tẹlọrun tabi ni ẹhonu le gba ile ẹjọ lori ibo naa.Okunrin yii sọrọ naa lakooko to n ba awọn oniroyin fọrọ jomitoro ọrọ lori agbeyẹwo wọn nipa ibo to waye ọhun.

Alaga ọhun to tun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu Action Alliance nipinlẹ Ogun tun rọ wọn lati gba abajade esi ti ajọ eleto idibo gbe jade gẹgẹ bi igbagbọ rere, ki wọn si sun siwaju.

O sọ pe ko yẹ ki wahala tabi awuyewuye kankan to le mu itajẹsilẹ waye lẹyin ibo to waye ọhun.

Sanyaolu tun sọ pe iṣe apapọ oṣelu ni lati tọ awọn ẹgbẹ oṣelu to wa labẹ wọn sọna nipa igbesẹ to ba yẹ ki wọn gbe nitori ki alaafia le jọba nipinlẹ Ogun.

O ni, "Bo tilẹ jẹ pe ajọ eleto idibo ti kede Arabinrin Ayọọla Elẹgbẹji, APC, gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nibi ibo atundi sile igbimọ aṣoju-ṣofin agbegbe Rẹmọ, ohun to ku wa ku lakooko yii ni bi isọkan yoo ṣe waye laarin gbogbo ẹgbẹ oṣelu. A  ko fẹẹ wahala kankan laarin wa, alaafia lo jẹ wa logun"

Sanyaolu tun sọ pe oun ranti nigba ti ibo ijọba ibilẹ waye nipinlẹ naa, tawọn ni gbọn mi si omi o to pẹlu ajọ eleto idibo, awọn gba kootu lọ fun idajọ.

O waa pari ọrọ ẹ pe," Nitori idi eyi ẹnikẹni to ba ni ikunsinu nipa ibo to kọja yii gba ile ẹjọ lọ, ki wọn ma ṣe ṣe ofin lọwọ ara wọn"

No comments:

Post a Comment

Pages