Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, akọwe fẹgbẹ ADC lapapọ ti sọ pe erongba wọn ni pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, ẹgbẹ naa yo ko awọn ọmọ Naijiria wọ ilẹ ileri nibi ibo to n bọ lọdun 2027.
O sọrọ naa nibi ayẹyẹ gbigba awọn oloṣelu tuntun lati inu ẹgbẹ PDP ati Labour wọnu ẹgbẹ oṣelu ADC, eyi to waye nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko.
Ẹni to ti figba kan jẹ minisita fọrọ abẹle lotileede yii fi idunnu ẹ han bawọn eeyan ọhun ṣe waa darapọ mọ ẹgbẹ APC nipinlẹ naa.
O ni ẹgbẹ ADC jẹ ibi tawọn ti jọ fimọsọkan lati wa ilọsiwaju fun orileede yii, o waa mu da wọn loju pe wọn ko nii kabamọ ati pe iṣẹ to wa nilẹ ajọṣe gbogbo wọn ni.
Lara awọn to wa nibẹ ni Ọgagun Tunji Sheile, to jẹ alaga PDP, tẹlẹ nipinlẹ Eko, George Ashiru, alaga ADC ni Eko, Dokita Abimbọla Ogunkẹlu atawọn mii ii.
No comments:
Post a Comment