Ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun, OGSIEC ti sọ pe Ogunjọ oṣu kẹsan-an, ọdun yii ni atundi ibo kanṣelọ yoo waye ni wọọdu kin in ni,nijọba ibilẹ Yewa South lati fi rọpo Ọnarebu Adekanbi Oluwaṣeun Ọlayinka, to doloogbe laipẹ.
Nibi ipade kan to waye ni gbọngan ilu Ilaro laarin OGSIEC atawọn araalu ọhun ni wọn kede akoko naa.
Gẹgẹ bi Oloye Arabinrin Rẹmilẹkun Ọlaọpa, to jẹ kọmiṣanna ni ẹka ofin fun ajọ naa to ṣoju alaga wọn, Babatunde Ọṣibodu, ṣe wi, o sọ pe igbesẹ naa ṣe pataki lati fi rọpo Oloogbe ọhun
O ṣalaye siwaju pe ibo naa ki i ṣe pe lati fi di aye to ṣofo nikan bi ko ṣe lati ṣe e bi ofin ijọba dẹmọkireesi ṣe laa silẹ.
Ọṣibodun tun fikun ninu ọrọ ẹ pe eyi jẹ lati fawọn eeyan wọọdu kin in ni ọhun ni iyi ati anfaani lati yan ẹni to ba wu wọn sipo kanselọ naa.
O waa mu da awọn eeyan agbegbe naa loju pe wọn yoo ṣeto idibo naa laini ojuṣaaju tabi segbe lẹyin oloṣelu kan.
Bakan naa awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ADC, APC,APGA ati PDP, ti wọn wa nibẹ gboriyin fun ajọ OGSIEC, fawọn iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe bẹẹ ni wọn tun rọ wọn lati ṣeto ibo ọhun lọna ti ko nii mu wahala wa.
No comments:
Post a Comment