Lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ ni ọfiisi ẹ, lo ti sọ pe nibi ti nnkan de bayii ko sẹgbẹ oṣelu to le sọ pe oun loun yoo jawe olubori amọ ọkan oun balẹ lori oludije wọn,Ọnarebu Solomon Oyekan Adeṣina
O sọ pe oju ti wọn fi n wo ẹgbẹ Action Alliance ti yatọ si ti tẹlẹ ati pe gbogbo akitiyan oun ni pe nigba ti yoo ba fi di ọdun 2027, awọn fẹẹ gbajọba ni.
Abayọmi to tun jẹ alaga AA tun sọ siwaju pe nnkan to jẹ oun logun ni bi ipinlẹ Ogun yoo ṣe pada bọ sipo ti ebi ati iṣẹ yoo fi kuro ninu aye awọn eeyan.
O lawọn akitiyan bẹẹ loun mu wọ ẹgbẹ oṣelu IPAC, toun jẹ alaga wọn. Ti ajọṣepọ fi wa laarin gbogbo alaga ẹgbẹ oṣelu.
O tẹsiwaju pe "Bi ẹ ba wo ipolongo oludije wa, Ọnarebu Oyekan to ti ṣe, ṣe lẹnu ya awọn araalu Ikenne, Sagamu, Rẹmọ ti wọn sọ pe ki lo n ṣẹlẹ. Ki ẹ si maa wo, ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ni.
" Amọ o mọ nnkan ti araalu n fẹ, nitori ọmọ Ṣagamu ni. O si n ṣe daadaa pẹlu ẹgbẹ"
Abayọmi waa sọ pe lagbara Ọlọrun didun lọjọ Satide maa jẹ, nitori awọn ti ṣepade pp pẹlu ọga awọn ọlọpaa ati ọtẹlẹmuyẹ lori eto aabo.
O ni loootọ ni ẹru n ba awọn araalu nitori nnkan ti wọn n gbọ pe gbogbo agbara ni ẹgbẹ to n ṣejọba nipinlẹ Ogun fẹẹ lo fun ibo naa.
O sọ pe nnkan toun kan mọ ni ọjọ Abamẹta yẹn yoo juwe ara ẹ nitori gbogbo oju lo n woo ati pe oun ni yoo juwe bi ibo 2027 yoo ṣe lọ.
Alaga IPAC ni ko si ọkan ẹni to ti balẹ ninu gbogbo awọn to n dije pe yoo wọle a fi ti ibo ba pari.
O waa rọ awọn eeyan agbegbe ti ibo naa yoo ti waye lati jade lọjọ naa, ki wọn wa dibo.
No comments:
Post a Comment