Nnkan kekere ni wọn kọkọ pe ọrọ naa, eyi to si di ranto nitori bi wọn ṣe lawọn ọlọpaa ọhun di gbogbo ọna tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun le lo fun ipolongo wọn.
Ohun ti wọn sọ pe awọn ọlọpaa naa sọ ni pe ko saaye fẹgbẹ oṣelu mii lati ṣepolongo lagbegbe ọhun ju APC nikan lọ.
Iwadii fi ye wa pe ko di akoko yii nirufẹ nnkan bẹẹ ti kọkọ waye niluu Iṣara, nibi ti wọn ko ti gba Solomon lati ṣe ipolongo, eyi ni wọn sọ pe o muu tẹsiwaju lọ si Rẹmọ, to si jẹ pe bakan naa ni.
A gbọ pe pẹlu ẹdun ọkan ni oludije naa fi fi ilu Iṣara to jẹ ilu abinibi ẹ silẹ, ti wọn si parọwa sawọn ọmọ ẹgbẹ lati ṣe suuru.
Ṣugbọn pabanbari ẹ lo waye niluu Rẹmọ, nibi tawọn ọlọpaa ṣe di gbogbo ọna, eyi to si mu inu bi Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, tiyẹn si fi ibinu sọrọ pe ki wọn ko gbogbo awọn nnkan ti wọn ko soju titi naa kuro, nitori titi ijọba apapọ ni, ko si bojumu.
Ọlọpaa kan Fred Ode, ọkan lara wọn ṣalaye pe aṣẹ tawọn gba lati oke lawọn mulo, pe ẹgbẹ oṣelu meji ko le ṣe ipolongo lọjọ kan naa ati lagbegbe kan naa.
Ibeere mii ti wọn tun beeere lọwọ ẹ pe ki lo de ti wọn ko jẹ ko ṣee ni Iṣara to wa tẹlẹ nigba ti APC ko ṣe nibẹ, ṣe wọn ni ọlọpaa naa da si agidi to si binu kuro lọdọ awọn oniroyin.
Amọ ṣa, gbogbo awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn sọ pe ọwọ agbara ni wọn lo fun Solomon Ọshọ.
No comments:
Post a Comment