Pẹlu bi eto iforukọsilẹ fun ibo ti ṣe bẹrẹ kaakiri orileede yii,ẹgbẹ to n wa ọna abayọ iyẹn The Alternative ti lo akoko naa lati gba awọn agbẹ nimọran lati kopa ti wọn ko ba ti ṣẹ bẹẹ tẹlẹ.
Nibi ipade kan to waye lọjọruu, Wẹside yii niluu Abẹokuta pẹlu ẹgbẹ awọn agbẹ kan ti wọn pe ni Agbẹ Gbelu Agro Network Limited, ni oludsilẹ The Alternative, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, ẹni ti Oluṣọla Salau, to jẹ alaga ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba ṣoju fun ti rọ awọn agbẹ naa lati lọọ forukọ silẹ.
Ṣowumi to ṣapejuwe ẹgbẹ awọn agbẹ ọhun gẹgẹ bi eyi to fẹsẹrinlẹ, eyi to sọ pẹlu igboya to ni si wọn pe bi wọn ba ro awọn eeyan naa lagbara, ounjẹ yoo tubọ pọ si nipinlẹ Ogun.
Oludasilẹ ẹgbẹ to n wa ọna abayọ yii tun sọ pe" Awọn eeyan yii ki i ṣe oloṣelu o, amọ wọn ṣe e fọkan tọ tọrọ ba di ki ayipada de ba idibo.
"Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, eeyan Ọmọọba Dapọ Abipdun ni,ati pe Dapọ Abiọdun ti lọ si orileede Brazil, o si ti mọ pataki iṣẹ ọgbin"
O waa fi akoko naa kesi Gomina Dapọ Abipdun lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ agbẹ naa nipa ironilagbara, nitori o ni wọn ṣe fọkan tan.
Ko to akoko yii ni Baalẹ awọn agbẹ Fohunọla Ajani ti tu aṣiiri pe awọn oloṣelu ni wọn jẹ anfaani ironilagbara latọdọ ijọba.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni lẹyin ti wọn ba ti gba ohun elo oko.ṣe lo ni wọn yoo lọọ ta, wpn yoo wa fi ọkọ ati ada nikan silẹ fawọn agbẹ.
Ninu ọrọ Ọjẹyinka Bamidele, ọkan lara awọn agbẹ, o bu ẹnu atẹ lu bijọba ṣe n ṣe idanilẹkọọ fawọn obinrin ati ọdọ ti wọn si n fawọn agba silẹ, eyi to sọ pe ko bojumu to.
O sọ pe ọpọ awọn anfaani to yẹ ki awọn agbẹ ti wọn ti dagba maa gba ni wọn ko fun wọn, o wa rọ ijọba ipinlẹ Ogun lati gbe igbesẹ lee lori.
No comments:
Post a Comment