Ẹ ye ko girigiri bo Arẹgbẹṣọla -ADC Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 18 August 2025

Ẹ ye ko girigiri bo Arẹgbẹṣọla -ADC Ogun


Ẹgbẹ oṣelu ADC, ẹka ipinlẹ Ogun ti tako bawọn oloṣelu kan ṣe n dunkoko mọ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, akọwe ẹgbẹ naa lapapọ, wọn ni kii ṣe nnkan to bojumu.

Ninu atẹjade kan ti Ọnarebu Mohammed MJG GKAF, to jẹ akọwe olupolongo ADC National Media Frontier, fi sita, lo ti fi aidunnu ẹ han si bi wọn ṣe fẹẹ doju ija kọ Arẹgbẹṣọla, to jẹ agba ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba lakooko ipolongo ibo to waye fun ti atundi ibo lagbegbe Rẹmọ, nipinlẹ Ogun.

O ṣalaye pe bi wọn ṣe fẹẹ maa dunkoko mọ ẹni to ti figba kan jẹ minisita fọrọ abẹle lorileede yii ko jẹ ohun itẹwọgba ti ko si yẹ ko maa ribẹ ninu ijọba dẹmokiresi taa n lo lọọ yii.

Mohammed ni bigba teeyan ba n tabuku ẹtọ ọmọniyan lawọn ka si, ko si yẹ ki wọn gba iru awọn ẹgbẹ oṣelu bee laaye.

O waa kesi awọn ẹṣọ alaabo lorileede yii lati tete wa nnkan ṣe si, ki wọn si rii pe aabo to peye wa fun Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC lapapọ.

Bakan naa lo tun ni ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa fọkanbalẹ, ki wọn si pa ofin ati pe bi nnkan yoo ṣe dara ni ko jẹ erongba ọjọ iwaju wọn.  

No comments:

Post a Comment

Pages