Aṣiwaju Orile- Imọ, Oloye Ọlakunle Ọlalekan, ti rọ ijọba ipinlẹ Ogun lati tete da si bi Ọba Reuben Ṣọgaolu, Olu Orile Imọ, atawọn oloye ẹ ṣe da oun duro lọna ti ko bofinmu.
O sọrọ yii nibi ipade awọn oniroyin to pe, o sọ pe lati ọdun 2018, ni Ọba to ti wa nibẹ tẹlẹ, to waja ti fi oun joye ọhun.
O ni gbogbo erongba Ọba Ṣọgaolu lati gba oye ọhun lọwọ oun fẹẹ fi da wahala silẹ laarin ilu, nitori oun ṣi wa laye, oun wa laaye.
Aṣiwaju Orile Imọ to tun jẹ alaga fun gbogbo awọn Baalẹ lagbegbe naa tun fi kun ọrọ ẹ pe Ọba Ṣọgaolu ko lẹtọọ lati gbe igbesẹ naa nitori titi di akoko yii, o si n jẹjọ lọwọ nipa ọrọ ọlọbade.
Bẹẹ lo mẹnuba ọpọ aṣeyọri ati idagbasoke to ti mu ba ilu naa latigba to ti wa lori oye ọhun. O waa rọ Ọba yii lati kọju mọ bi ilọsiwaju yoo ṣe tubọ ba ilu, ju pe ko maa dunkoko mọ awọn eeyan.
Aṣiwaju Orile Imọ yii la gbọ pe o waa lara awọn ti wọn jọ dupo ọba ilu ọhun ko to di pe o ja mọ Ṣọgaolu lọwọ.
Lara awọn ti wọn tun sọrọ nibẹ ni Baalẹ Kajọla, Oloye Ayinde Gbadamọsi, to ṣoju awọn yooku ẹ, oun naa rọ ọba naa lati yi ipinnu ẹ pada.
Bakan naa ni Oloye Jimoh Ọlọrunṣogo, to jẹ olori awọn ọdọ niluu ọhun naa sọ pe awọn tako igbesẹ naa bẹẹ lawọn ko faramọ.
No comments:
Post a Comment