-Alabaṣiṣẹ pọ ni wọn
Ṣugbọn oriṣiriṣi ọrọ oṣelu lawọn kan sọ lati tẹmbẹlu ọkunrin naa tawọn kan si sọ pe ọdalẹ ni ati pe ko yẹ ko ba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ja, nitori awọn nnkan ti wọn sọ pe o ti ṣe fun un.
Bo tilẹ jẹ pe lati bi ọdun meloo kan sẹyin ni aarin Ọgbẹni Arẹgbẹsọla ati Aarẹ ti daru, gbogbo ọna si ni wọn ni Gomina tẹlẹ ọhun da lati jẹ ki alaafia waye, amọ tawọn arijẹ ninu mọdaru tubọ bu epo si.
Ko si pẹ laipẹ yii ti ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun fi kede pe awọn yọ Ọgbẹni danu lẹgbẹ APC, ti wọn ni awọn ko ba ṣe mọ.
Nitori igbagbọ tawọn aṣaaju oloṣelu ninu ẹgbẹ PDP ati APC ni ninu Arẹgbẹṣọla lo mu ki Abubakar Atiku atawọn kan lọọ ṣe ipade pọ pẹlu Minisita tẹlẹ naa lati wa ọna abayọ si bi atunṣe yoo ṣe deba oṣelu orileede wa.
Ko si pẹ ti wọn fi pamọpọ lati darapọ mọ ẹgbẹ ADC, nibi ti David Mark ti jẹ alaga wọn, nigba ti wọn si fi Arẹgbẹṣọla jẹ akọwe, tawọn mejeeji si jọ n dele lọwọ.
Loju ẹsẹ ni Arẹgbẹṣọla ti bẹrẹ iṣẹ, to si n ṣe ifikunlukun kaakiri, amọ sibẹ, ibajẹ ẹ lawọn ọta ẹ nidii oṣelu n wa, amọ to kọ ipakọ si wọn, ti ko ri ti wọn ro.
Ni bayii, ọkan lara awọn to sunmọ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti tan imọlẹ sawọn ahesọ tawọn kan maa n sọ nipa Gomina Ọṣun tẹlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni lọdun 2018, nigba ti Arẹgbẹṣọla fipo gomina silẹ, o lọọ ba Aṣiwaju nile ẹ pe oun fẹẹ rin irinajo lọ si Amẹrika, wọn le fẹẹ yẹ CV, oun wo pe ki wọn gba.
Onitọhun tun ṣalaye siwaju pe "Kin ni mo fẹẹ fi ṣe, a nilo ẹ mọ, a ti lo ẹ, bi a ṣe fẹẹ lo ẹ'
O ni ilu oyinbo ni ọga oun wa, to fi ri orukọ ẹ ninu iwe iroyin ti Buhari fun nipo minisita, o ni oun fi tan imọlẹ fawọn eeyan pe Oloogbe Buhari lo fun Arẹgbẹṣọla nipo naa kii ṣe Tinubu.
Bakan naa ni onitọhun tun ṣalaye siwaju pe Arẹgbẹṣọla ki i ṣe ọmọọdọ tabi ọmọleewe ti Tinubu kọ ni oṣelu, alabaṣiṣẹ pọ ẹ ni.
O ni ẹni to ṣiṣẹ ọpọlọ to jẹ ki Tinubu ṣe aṣeyọri laarin ọdun 1999 si 2007, o ni Arẹgbẹsọla ni, nipa awọn iṣẹ idagbasoke atawọn imayedẹrun.
No comments:
Post a Comment