Ayinla Ẹgba fẹgbẹ oṣelu ADP silẹ nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 17 July 2025

Ayinla Ẹgba fẹgbẹ oṣelu ADP silẹ nipinlẹ Ogun



Gbajumọ sọrọsọrọ ori redio nni, to tun jẹ oludije fun ipo alaga labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP nibi ibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Ọlalekan Ayinla Shoyinka, tọpọ mọ si Ayinla Ẹgba, lo ti kede pe oun ti fi ẹgbẹ naa silẹ.

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lonii, lo ti kọkọ dupẹ lọwọ ẹgbẹ naa bi wọn ṣe gba oun tọwọ tẹsẹ lakooko to fi wa pẹlu wọn.

O sọ pe latigba ti ibo ọhun ti n lọ lawọn eeyan paapaa awọn ololufẹ ẹ ti n beeere pe bawo ni ọjọ iwaju oun nidii oṣelu toun si sọ fun wọn pe ki wọn fọkanbalẹ takoko ba to oun yoo jẹ ki wọn mọ.

Amọ ni bayii, Ayinla Ẹgba ti wa kede pe oun ko ni nnkan ṣe pọ mọ pẹlu ADP ipinlẹ Ogun ati pe ẹgbẹ oṣelu tuntun ti yoo darapọ mọ yoo farahan laipẹ.

Ọkunrin naa sọ pe " Lẹyin gbogbo ifikunlukun mi pẹlu awọn aṣaaju mi atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti imọ wọn papọ mọ temi ni gbogbo wọọdu mẹẹẹdogun to wa nijọba ibilẹ Abeokuta South, emi Oloye Ọlalekan Shoyinka atawọn ẹgbẹ mi, 'Ayinla Ẹgba Movement' ti fẹgbẹ ADP silẹ.

"Mo ti fọrọ naa to awọn agba ẹgbẹ ọhun leti, ti mo si mọ pe wọn yoo gba gẹgẹ bi igbagbọ, eyi to tumọ si pe erongba ati ala wa ko wulo ninu ẹgbẹ naa"

O waa mu da awọn araalu loju pe gbogbo bi nnkan ba ṣe n lọ ni yoo maa fi to wọn leti.

No comments:

Post a Comment

Pages