Godwin Ọtunla to jẹ ọga agba fawọn aṣọbode nipinlẹ Ogun ti tun sọ nipa aṣeyọri ti wọn ṣe laipẹ yii nips mimu mọto to fẹẹ ko igbo wọlu.
O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin fọrọjomitoro ọrọ nipa aṣeyọri wọn, o sọ pe lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii ni wọn ta wọn lolobo pe tirọọki mẹsidisi kan ti nọmba ẹ jẹ EPE 597 LA, torukọ dẹrẹba ẹ jẹ Williams Asare.
O fikun ọrọ ẹ pe agbegbe Mobil Challenge niluu Ibadan lo n gbe, oun lo sọ pe o wa mọto ti igbo wa ninu ẹ ọhun.
Ọtunla ṣalaye siwaju pe lẹyin tawọn ṣayẹwo nnkan ti wọn we pọ ọhun lawọn rii pe igbo ni loju ẹsẹ lawọn si ti gbe ọkọ naa lọọ si oluuleṣẹ wọn.
Lara awọn nnkan to lawọn tun ṣakiyesi ni igbo ọhun to lẹ ni ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹta.
O sọ pe bo tilẹ jẹ pe ko tii ju ọsẹ meji lọ tawọn ṣe iru ipade oniroyin bẹẹ ṣugbọn idunnu nla lo jẹ pe awọn tun ṣaṣeyọri miiii.
O wa gboriyin fawọn oṣiṣẹ fawọn iṣẹtskuntakun ti wọn n ṣe, ti wọn ko si gba irẹwẹsi laaeye.
Bẹẹ lo tun lo anfaani naa ki ọga wọn agba Bashir Adewale fun ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan an si lagbaaye.
No comments:
Post a Comment