ÀÌMỌ̀KAN ÀTI ÌGBÉRAGA TÍ Ó MÁA Ń WÁYÉ NÍGBÀ TÍ A KÒ BÁ GBỌ́ ORÚKỌ ÀWỌN ÈÈYÀN ÀTI IPÒ WỌN YÉ NÍ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 3 July 2025

ÀÌMỌ̀KAN ÀTI ÌGBÉRAGA TÍ Ó MÁA Ń WÁYÉ NÍGBÀ TÍ A KÒ BÁ GBỌ́ ORÚKỌ ÀWỌN ÈÈYÀN ÀTI IPÒ WỌN YÉ NÍ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ





Mo ṣe akiyesi kan lọpọ igba ti wọn ba beere pe kin ni orukọ wọn, wọn yoo sọ pe ouukọ wọn ni Dokita Lagbaja, Ọjọgbọn Tẹmẹdu, ẹlomii yoo tiẹ sọ pe Oloye kin ni kan lohun.

Mo ranti pe igba kan ti ẹnikan binu pe wọn ko fi Ọtunba kun orukọ oun, nigba ti wọn fẹẹ ṣafihan oun.

Mo fẹẹ ki ẹ mọ kin ni kan daju pe ọjọgbọn ki i ṣe orukọ bẹẹ naa lo si jẹ pe oye naa ki i ṣe orukọ.

Bi ẹnikan ba sọ pe awọnlẹ (sọfiọ) lagbaja ni oun, ko boju mu, ohun to gbọdọ jẹ ni orukọ mi ni Gbenga Adeoye, mo ṣiṣẹ gẹgẹ bi awọnlẹ.(Ẹni to kọ iroyin yii ki i ṣe awọnlẹ oo)

Fifi orukọ oye kun orukọ ko mu itumọ gidi gan an jade,o si ti n wọpọ lawọn ijọ Ọlọrun.

Ọpọ wọn ni wọn fẹran lati jẹ ki wọn fi Ajihinrere kun orukọ wọn, koda awọn ọdọ to n kọrin ninu ṣọọṣi n fẹ ki wọn fi Ajinrere kun orukọ wọn.

Eyi wọpọ laarin awọn eeyan nilẹ Afrika ti ko si bojumu.

Mo ranti nipa ti mo wa nilẹ Amẹrika,ti mo n kẹkọọ ni Havard, Orukọ ti wọn jẹ gẹlẹ la n pe wọn laifi oye tabi ipo ti wọn wa kun un, bii Mike, John.Bi a ṣe maa n pe wọn niyii, 'Mo fi akoko yii pe John Bedford. John jẹ ọjọgbọn isakoso okoowo.

Awọn eeyan nla bi Buọ Gbile Akanni si n jẹ Buọda.

Ọpọ awọn ọdọ akoko yii ni wọn fẹẹ ki wọn maa pe wọn ni Apọsu,bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni agbara ẹmi mimọ, to fi le ṣafihan wọn, wọn fẹẹ ṣafarawe awọn Apọsu ti wọn ni ẹri to le fi wọn pe wọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.

Ko ya wa lẹnu pe ọpọ awọn to pe ara wọn ni biṣọọbu ati apọsu ni wọn jẹ ayederu, nitori wọn ko ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ.

Mo mọ olowo kan to jẹ pe inu rẹ ki i dun ti wọn ko ba fi Alaaji kun orukọ ẹ.

Ohun to mu ọrọ yii jade ko ṣe lẹyin nigba tawọn aṣofin agba ṣayẹwo awọn ti wọn yan, ti ọkan lara wọn binu pe awọn aṣofin ko fi ọjọgbọn kun orukọ oun, ti wọn pe oun ni ọgbẹni.

Eyi jẹ ọkan lara iṣoro to koju wa lorileede Naijiria ati ilẹ Afrika.

O gbọdọ lawọn ipo kan ti eeyan de ko to di pe awọn eeyan fi orukọ oye ẹ kun orukọ ẹ, irufẹ ipo bẹẹ ni Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka wa lonii.

Irufẹ awọn eeyan bẹẹ tun ni Pasitọ E A Adeboye ati Pasitọ Kumuyi, to jẹ pe iṣoro lo ma jẹ fawọn eeyan lati ma fi pasitọ kun orukọ wọn.

Iyalẹnu lo maa n jẹ ti ẹnikan ba sọ pe oun fẹẹ ṣatunṣe orukọ oun ki i ṣe Ọgbẹni Lagbaja bikoṣe Ọjọgbọn tabi Dokita tabi Ọtunba lagbaja.

Aimọkan to ṣe wọn ni pe wọn ko mọ iyatọ laarin kin ni orukọ ẹ tabi kin ni orukọ oye ẹ, 

Eyi ni ọna to le gba lati  le fi dahun, sọ orukọ ẹ, iru eeyan to jẹ ni ṣoki. Orukọ mi ni Olugbenga Adeyẹmi Adeoye. Mo wa lati ipinlẹ Ogun,Mo jẹ Ọjọgbọn ni ẹka iṣiro tsbi ofin tabi  ni yunifasiti bayii.

Koda gan-an to ba jẹ pe orukọ ẹ nikan ni wọn beere, waa kan sọ pe orukọ mi ni Olugbenga Adeoye.

Irufẹ nnkan bayii ni Adams Oshiomhole, ṣalaye nigba to n sọ fun ẹni ti wọn ṣayẹwo fun gẹgẹ bi kọmiṣanna fajọ eleto pe ọjọgbọn ko si lara orukọ ẹ,( Bo tilẹ jẹ pe mo tun fẹẹ ko tubọ tan imọlẹ si)

Mo n gbọ ti ẹnikan sọ pe Senetọ Lagbaja lorukọ oun, iyẹn ko dara to kaka ko sọ pe Olugbenga Adeyemi Adeoye lorukọ mi ti mo jẹ aṣofin to n ṣoju ẹkun bayii nile igbimọ aṣofin.

Awọn eeyan lo le fi orukọ oye tabi ipo ẹ pe ẹ, ki i ṣe iwọ fun ara ẹ iyẹn ti wọn ba beere ni o.

Mi o fẹẹ ki ẹnikẹni ṣi mi gbọ rara, to ba tiẹ kawe gboye fun imọ dokita, jẹ ko wa ninu kaadi ẹ, koda to bs fẹẹ darukọ ẹ bii Dokita Lagbaja, eyi yoo mu iyatọ ba ataja atẹran ti wọn pe ara wọn ni dokita.

Mo tun ṣakiyesi pe ọpọ awọn ti wọn pe ara wọn ni dokita ni wọn ko kawe tabi ṣiṣẹ iwadii kankan lojiji ni wọn sọ ara wọn di dokita yiii.

O kan tiẹ le beeere awọn ibeere kan ti waa fi mọ pe ayederu dokita ni. Lara ẹ ni; 
Kin ni iṣẹ iwadii ẹ dale lori?
Ta ni alamujo iṣẹ iwadii ẹ ?
Ta ni olukọ ẹ lati ita?
Ta ni olukọ nile?
Kin ni awọn afikun imọ ẹ?
Igba wo ni wọn kede orukọ ẹ gẹgẹ bii dokita

To ba beere awọn ibeere yii lọwọ ayederu to loun gba  oye ọmọwe iyẹn dokita yii, waa rii pe kaunkaun ni yoo maa jade lẹnu ẹ.

Ẹdun ọkan lo jẹ pe lawọn ileewe giga wa gbogbo ọpọ olukọni wọn lo jẹ ayederu ti wọn ko ni iwe ẹri gidi lọwọ.Bawo ni a ṣe fẹẹ wa gbogun tiwa ibajẹ lawọn ileewe wa gbogbo.

Irufẹ awọn olukọni bẹẹ ni wọn maa n beere owo lọwọ awọn akẹkọọ wọn.

Bẹẹ ni mo tun gbọ pe a ni iru awọn eeyan bẹẹ lawọn ileewe girama.

Ọpọ awọn olukọ yii ni wọn ko ni ẹri ọkan ti wọn n ta ipo fawọn ọmọleewe wọn, awọn ti ko ba rowo fi silẹ ni wọn maa n fidi ẹ rẹmi.

Ohun to dara ni bi wọn ko ba ni ọpọ olukọ ati olukọni lawọn ileewe ju pe ki wọn maa gba awọn ti yoo ma bawọn loju jẹ lọ.

Abajọ idi niyii ti ko le fi ya mi lẹnu pe ọpọ ọmọleewe ti wọn ṣedanwo WAEC, NECO ati JAMB ni wọn nigbagbọ ninu jiji iwe wo lakooko idanwo naa nitori wọn ti mọ pe wọn yoo fi owo ṣe ni.

NI IPARI

Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe orukọ tabi ipo ki i ṣe orukọ bẹẹ naa iṣẹ yatọ si orukọ.

Bi a ba fẹẹ fi ọla fẹni to yẹ,a gbọdọ sa fun a ṣe afomọ awọn ayederu ti wọn lawọn gba imọ digirii laarin wa.

A gbọdọ lawọn olukọ ti wọn da tọ lẹnu igbin, ti wọn gbọọrọ jẹka,lawọn ileewe giga wa, eyi yoo jẹ ki s ni awọn akẹẹkọ to ṣe fọkan tọ pẹlu iwe ẹri gidi lọwọ.
Gbenga Adeoye to kọ akọsilẹ yii jẹ agbẹjọro,onimọ iṣiro, to si tun gboye ọmọwe nipa iṣakoṣo okoowo. Bẹẹ ni ẹ le ksn si wa ni dga@gbengaadeoye.com

No comments:

Post a Comment

Pages