Ko si idajọ kan to yọ Macgregor nipo ọba Orile-Ilawọ- Aarẹ Babatunde Doherty - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 28 January 2025

Ko si idajọ kan to yọ Macgregor nipo ọba Orile-Ilawọ- Aarẹ Babatunde Doherty



 Aarẹ Babatunde Doherty, to tun jn agbẹjọro ti sọ lorukọ awọn oloye Ilawọ, pe ko si ootọ ọrọ ninu idajọ kan ti wọn ni ile ẹjọ giga niluu Abẹokuta paṣẹ pe ki Olu-Orile Ilawọ, Ọba Alexander Macgregor, ko fipo naa silẹ tabi ko ye pe ara ẹ ni ọba ilu naa mọ.

 

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita ni alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo ti sọ pe eyi ni lati sọ fun gbogbo araalu pe ko si idajọ kankan to waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, o ni koda wọn ti sun igbẹjọ to n lọ lọwọ lori ẹjọ naa siwaju di ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta ọdun yii.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’ Akiyesi awa igbimọ oloye Ilawọ lọ sibi awọn iroyin kan ti wọn pin kaakiri ti wọn sọ pe ile ẹjọ giga, to wa ni Abẹokuta ti wọn ni nọmba ẹ jẹ No 789/2022, ti wọn ni wọn da pe wọn rọ Olu Orile Ilawọ nipo ọba

 

‘’ Mo fẹẹ sọ di mi mọ pe iroyin ọhun ko jẹ ootọ, nitori titi akoko taa sọrọ yii, ẹjọ naa ṣi wa niwaju ile ẹjọ. A fẹẹ jẹ ko di mimọ fun araalu pe idajọ kankan ko waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kin in ni, koda wọn ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii.

 

Doherty tun fikun ọrọ ẹ pe awọn ko gbọ nipa aṣẹ ile ẹjọ ọhun, aṣẹ tawọn kan mọ tile ẹjọ pa ni pe ki gbogbo nnkan ṣi wa bo ṣe wa laarin awọn mejeeji, titi ti idajọ yoo fi waye.

 

O ni itumọ nnkan ti adajọ naa sọ ni pe ki gbogbo ẹ wa ṣi wa bo ṣe wa ko to di pe wọn pe ẹjọ. O ni  wọn ti yan Olu Orile Ilawọ, ti wọn si ti fi jọba ko to di pe wọn pe ẹjọ.Bẹẹ lo sọ pe ẹjọ ko tẹ milọrun kan si wa nilẹ, eyi to ni yoo sọ boya idajọ yoo waye.

 

O waa sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba gbe iroyin jade pe wọn ti rọ ọba loye kan gbe igbekugbe jade ni. Nitori idi eyi, wọn wa rọ gbogbo awọn ọmọ bibi ilu Ilawọ, ọrẹ ati ojulumọ lati ma ṣe gba iroyin naa gbọ. Ati pe awọn oloye ilu Ilawọ ṣi wa lori ẹ, to si ni gbogbo liana ati ofin to ba tọ lawọn yoo tẹle lori ọrọ 

No comments:

Post a Comment

Pages