Eyi lawọn aṣeyọri wa lọdun to kọja-Ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 28 January 2025

Eyi lawọn aṣeyọri wa lọdun to kọja-Ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun




Mohammed Shuaib, ọga agba fun ẹṣọ aṣọbode, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe miliọnu lọna igba naira ni wọn pa wọle si oṣuwọn apo ijọba lọdun to kọja pẹlu ileri pe wọn yoo pa ju bẹẹ lọdun ta a wa yii.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n sọ nipa aṣeyọri wọn lọdun 2024,eyi to waye ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idiroko. O sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ ipenija lawọn koju nipasẹ awọn onifayawọ ṣugbọn ko mu awọn rẹwẹsi rara.

Shuaib tun fikun ọrọ ẹ pe apapọ owo ti wọn pa sapo ijọba lọdun jẹ miliọnu lọna igba ole diẹ Naira. O ni lara awọn nnkan ti wọn tun gbọ lọwọ awọn onifayawọ lẹyin igbo ni apo irẹsi, epo pẹntiroolu, ọta ibọn, aṣọ aloku, mọto tokunbọ, taya aloku, oku adiẹ, atawọn nnkan mi-ii ti aropọ owo wọn jẹ biliọnu ka ole diẹ naira.

Loju ẹsẹ ni Shuaib fa awọn apo ti wọn di igbo ti wọn gba naa le ajọ NDLEA lọwọ. O waa dupẹ lọwọ ọga agba ajọ ẹṣọ aṣọbode lorileede yii, Bashir Adewale Adeniyi fun atilẹyin rẹ atawọn liana to n gbekale lati jẹ ki ileeṣẹ naa maa pawo wọle sapo ijoba apapọ.

Bẹẹ lo sọ pe ọga wọn yii tun lo awọn  iriri ẹ lati fi ma dari iko aṣọbode, eyi to ni o ti mu aṣeyọri wa. Bakan naa lo tun fi imọriri ẹ sawọn ẹṣọ alaabo yooku nipinlẹ Ogun fun ifọwọsowọpọ wọn lori awọn iṣẹ ti won ti se.

Shaib waa rọ awọn araalu lati maa fi awọn nnkan to ba n ṣẹlẹ lagbegbe wọn sọwọ si wọn.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages