A maa fi ajọ EFCC fi gbe Gomina Dapọ Abiọdun laipẹ-Fẹmi Ṣoluade - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 15 January 2025

A maa fi ajọ EFCC fi gbe Gomina Dapọ Abiọdun laipẹ-Fẹmi Ṣoluade

Wahala nla lo tun fẹẹ bẹ silẹ ni agbo oṣelu nipinlẹ Ogun bayii laarin apapọ ẹgbẹ oṣelu ti wọn pe ni Coalition for United Political Parties (CUPP) ati Gomina Dapọ Abiọdun, nigba tawọn ẹgbẹ naa ṣọ pe awọn ṣetan lati gbe mu ẹjọ Gomina lọọ sọdọ ajọ to n ri si gbigbogun tiwa ibajẹ ati ṣiṣowo ilu baṣubaṣu iyẹn EFCC.

 

Nibi ipade oniroyin kan ti ẹgbẹ naa ṣe lana-an, Ọjọọru, Wẹsidee, ni alaga wọn Fẹmi Ṣoluade ti bu ẹnu atẹ lu bi Dapọ Abiọdun ṣe n sowo ilu mọkumọku, ti wọn lo si pa awọn iṣẹ akanṣe amayedẹrun to yẹ ko ṣe fawọn araalu ti.

 

Gẹgẹ bi ọrọ ti Fẹmi Ṣoluade  sọ, o ni ijọba to n lọ lọwọ nipinlẹ ọhun ti sọ ida ọgọta o le kan araalu sinu oṣi ati ipọnju ti wọn si n fojoojumọ jẹ ki ọrọ aje lọ sẹyin.

 

O fikun ọrọ ẹ pe  bigba ti Dapọ Abọdun ba sọ awọn eeyan Ogun sinu igbekun ati oko ẹru lọrọ ri lati nnkan bii ọdun meji sẹyin,kaka ki wọn si wa ojutu sii. ṣe lo ni wọn da kun ni.

 

Ṣoluade to tun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Ogun, ṣalaye siwaju pe awọn fi ipade oniroyin tawọn ṣe yii fi pe Abiọdun lati tete wa atunṣe lori iṣakoso lọna ti ko mu itumọ da ni.

Ọkunrin naa tun sọ pe ‘ Mo fẹẹ fi ye awọn araalu nitori akakun ati bi wọn se pa awọn iṣẹ imayedẹrun ti, lo jẹ ki awọn ọna wa fojoojumọ bajẹ si, to ti di panpẹ iku fawọn eeyan

‘’Iṣẹ awa apapọ ẹgbẹ oṣelu CUPP ni lati maa jẹ kawọn araalu bi nnkan ba ṣe n lọ ninu iṣejọba to ba wa lode ati lati mu igbe aye wọn dẹrun’’

Bẹẹ lo tun fẹsun kan Gomina lori bo ṣe n gbeṣẹ agbaṣẹṣe fawọn ti ko mọṣẹ ṣe, to si n tabuku ipinlẹ ọhun.Bẹẹ lo ni ko tẹle awọn igbesẹ to yẹ ko to gbeṣẹ fawọn eeyan ọhun.

“Gbogbo awọn ọna wa lo wa ninu ewu nla nipinlẹ yii nnkan ta kan maa n ri ni pe kawọn agbaṣẹṣe ti wọn gbesẹ fun ri patako wọn mọlẹ, ti wọn ko si ni ko irinṣẹ wọn debẹ, o buru jai gan-an ni.

Ṣoluade waa sọ pe ẹgbẹ CUPP ti wa bẹrẹ igbesẹ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn agbọjọro labẹ ofin ọdun 2011, tipinlẹ Ogun lati beere lọwọ ileeṣẹ to n ri si eto isuna labẹ Dapọ Okubadejọ ati eyi to n ri ọrọ ile labẹ Jagunmolu Akande Ọmọniyi, pe ki wọn fi awọn iwe  owo ati orukọ atawọn ti wọn gba ile sọwọ si wọn laarin ọjọ meje.

O ni ẹgbẹ CUPP, ti n gbe iogbeṣẹ lati fẹjọ Gomina sun ajọ EFCC ati ICPC lori awọn ti wọn gbe iṣẹ akanṣe fun lori ọna, ti wọn ti pa ti,bẹẹ naa ni bi Dapọ Abiọun ati APC ṣe n ṣowo kumọkumọ, wọn wa rọ Gomina lati mura silẹ fawọn lati pade nile ẹjọ

 

No comments:

Post a Comment

Pages