Idunnu lo ṣubu layọ fun alaga fẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, Oloye Sikirulai Ogundele nigba to gboye imọ ijinlẹ Ọmọwe taa mọ si Dokita.
Nibi ayẹyẹ ọhun to waye lọjọ Ẹti Furidee lọgba ileewe giga yunifasiti tawọn olukọni Tai Ṣoarin, to wa ni Ijagun, niluu Ijẹbu-Ode.
Nibẹ ni agba oṣelu to tun jẹ olokoowo nla ti gboye imọ ijinlẹ Dokita lori ẹkọ "Political Science, Peace and Conflict Resolution' eyi to nii ṣe pẹlu oṣelu ati ọna ti wọn le maa gba wa abayọ si alaafia.
Ninu ọrọ rẹ lo ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore-ọfẹ to fun un lati ṣe aṣeyọri nidii ẹkọ ọhun, nitori pe ko rọrun.
O sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ idojukọ lo waye lakooko to n kẹkọọ naa amọ oun dupẹ pe Ọlọrun foun ni ẹmi ati alaafia lati gboye ọhun.
O fikun ọrọ ẹ pe,"Adupẹ pe mo ka iwe yii pẹlu ipinnu eyi tí yoo nipa ninu awọn to tọ wa lẹyin.O si ṣee ṣe ki n di olukọni lọjọ iwaju"
Nigba to n sọ nipa iriri ẹ, o sọ pe gbogbo nnkan teeyan ba fẹẹ ṣe laye yii ko fọkan si,nitori oriṣi ọpọ iṣoro lo maa koju lọna.
O ni paapaa awọn toju wa lara wọn gbogbo eeyan lo fẹẹ woo pe bawo lo ṣe ṣee idanwo yii, o ni ki i ṣe olukọ nikan,atawọn eeyan pẹlu ni wọn fẹẹ mọ nnkan to kọ silẹ.
Bẹẹ lo sọ pe pẹlu oye tuntun to ṣẹṣẹ gba nileewe giga yunifasiti yii ko di oṣelu ati okoowo to n ṣe lọwọ gbogbo ẹ tubọ ṣiṣẹ pọ fun rere ni.
No comments:
Post a Comment