Àwọn Ẹ̀gbá yarí o; Wọ́n làwọn nipò gómìnà kàn lọ́dún 2027 - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 29 November 2024

Àwọn Ẹ̀gbá yarí o; Wọ́n làwọn nipò gómìnà kàn lọ́dún 2027



Bi nnkan ṣe n lọ yii afaimọ ko ma jẹ pe ko ni ti di ọdun 2027, ti ibo gbogbogboo yoo waye ki wahala to bẹrẹ nipinlẹ Ogun lori ipo gomina, nitori bawọn Ẹgba ṣe paroko ranṣẹ pe ki Ijẹbu ati Yewa gbagbe ẹ awọn lo kan.

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ọhun ti n ja rainrain nilẹ tẹlẹ, ti wọn si n sọ labẹlẹ ṣugbọn lọsẹ to koja yii ni Ambasedọ Ṣarafa Tunji Iṣọla, to ti figba kan jẹ aṣoju orileede yii lorileede United Kingdom, tan imọlẹ si ọrọ naa.

Lakooko ti agba oṣelu yii ti tun ti figba kan jẹ minisita lorileede yii n ba awọn obinrin kan ti wọn pe ni ‘Women in Politics’  nigba tawọn yẹn lọọ ki fun ọjọọbi ẹ, lọsẹ to kọja lo ti gba wọn nimọran lati yẹra fun oṣelu ẹtanu ati iyapa, nitori ko le mu eṣo rere kan ba ilu.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ko sigba tawọn Yewa jade lati dupo gomina tawọn Ẹgba ki i dide lati gbarukutu ti wọn. O ni lọdun 2011, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, to jẹ olori orileede yii duro gbọingbọin lati nigba ti wọn fa Oloogbe Tunji Olurin silẹ, toun si jẹ alakoso olupolongo.

O sọ siwaju pe, ‘ Lọdun 2019, Ọbasanjọ ṣatilẹyin fun Gboyega Nasir Isiaka, nigba ti Sẹnetọ Ibikunle Amosun, wa nipo gomina toun wa lẹyin Adekunle Akinlade, temi si jẹ alakoso ipolongo.

‘’Bẹẹ lọrọ tun ṣe ri lọdun 2023, nigba ti Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ṣatilẹyin fun Biyi Ọtẹgbẹyẹ, bi ẹ ba si ri gbogbo alaye ti mo sọ kalẹ yii, ẹ o rii pe awa taa jẹ ọmọ Ẹgba ni aarin gbungbun Ogun maa n wa lẹyin Yewa lati di gomina’

Iṣọla tun fikun ọrọ ẹ pe Ọlọrun fawọn eeyan gidi jinki ipinlẹ Ogun, ti wọn si ti kopa to jọju lati le mu idagbasoke ba ipinlẹ ọhun ati orileede lapapọ, o waa ni akoko ti wa to lati jẹ ki ifẹ iṣọkan ko jọba.

O waa fi ipinlẹ Eko ṣapẹẹrẹ pe ojoojumọ ni idagbasoke n de ba wọn nitori wọn ko fi ẹtanu oṣelu ṣiṣẹ wọn, toun si nireti pe awọn naa le ṣe bẹ nipinlẹ Ogun.

O ni ko si nnkan to buru ju ka ni wọn tẹsiwaju iṣẹ ti awọn Gomina tẹlẹ naa ti ṣe bii Ṣẹgun Ọṣọba, Gbenga Daniel, Ibikunle Amosun titi dori Dapọ Abiọdun.

Nigba to dahun si ibeere lori boya o nifẹẹ lati jade dupo, Ambasedọ Iṣọla sọ pe ẹni ti gbogbo Ẹgba ba panupọ lati fa a kalẹ ni yoo jade dupo.

Gẹgẹ bo ṣe wi, igba akọkọ ree ti gbogbo Ẹgba yoo fẹnuko pe ki wọn pin ipo gomina wa aarin gbungbun Ogun to jẹ ilẹ Ẹgba.


No comments:

Post a Comment

Pages