Idunnu ṣubu layọ nigba ti wọn kede Ogbẹni Kunle Idowu tọpọ awọn eeyan mọ si KI gẹgẹ bi oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ Ogun, iyẹn Ọmọọba Dapọ Abiọdun.
Okunrin naa ẹni to ti figba kan jẹ alaga fawọn aṣoju-kọroyin ati igbakeji alaga fẹgbẹ awọn oniroyin nipinlẹ Ogun la gbọ pe akọwe ijọba ipinlẹ naa, Tokunbọ Talabi, kede fun ipo tuntun ọhun.
Ninu lẹta ti akọwe ijọba naa fi ranṣẹ yii lo ti ṣalaye pe Gomina Dapọ Abiọdun ti fọwọ sii, eyi to si ti bẹrẹ lati ọjọ kẹta, oṣu yii.
Odu ati agbs ọjẹ nidii iṣẹ iroyin ni Kunle Idowu to si ti kawe gboye lawọn ileewe kan,nibi to ti kọ nipa iṣẹ iroyin.
Ni bayii, ẹgbẹ awọn oniroyin nipinlẹ Ogun ti dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun, lori bo ṣe yan ọkan lara wọn fun ipo tuntun naa.
No comments:
Post a Comment