Nitori okunkun biribiri: Awọn ọdọ Ipẹru- Rẹmọ fun ileeṣẹ mọnamọna IBEDC lọjọ meje lati da ina wọn pada - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 4 May 2024

Nitori okunkun biribiri: Awọn ọdọ Ipẹru- Rẹmọ fun ileeṣẹ mọnamọna IBEDC lọjọ meje lati da ina wọn pada

Awọn olugbe niluu Ipẹru- Rẹmọ ti fun ileeṣẹ mọnamọna iyẹn IBEDC lọjọ meje lati da ina wọn ti wọn ti mu lọ lati nnkan bi oṣu mẹta sẹyin pada,ko to di pe awọn gbe igbesẹ to lagbara.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lati bi oṣu mẹta ni wọn ti sọ awọn eeyan agbegbe naa sinu okunkun biribiri, ti wọn ko si wa ọna abayọri sii titi di akoko yii.

Wọn ni ẹdun ọkan lo jẹ fawọn pe ileeṣẹ mọnamọna kuna lati sọ ohun to ṣokunfa bi wọn ṣe sọ ilu ọhun di okunkun.
Awọn ọdọ naa ti wa yari pe pẹlu gbogbo igbesẹ tawọn gbe ti wọn ko jẹ ko so eso rere, awọn naa ti waa ṣetan lati ja fẹtọọ wọn

Idi niyii ti wọn fi rọ ileeṣe IBEDC ọhun lati tete da ina wọn pada fun wọn laarin ọjọ meje bi bẹẹ kọ awọn yoo bẹrẹ iwọde kaakiri.

Iyẹn nikan kọ, awọn ọdọ yii ni gbogbo ileeṣẹ mọnamọna to wa niluu ọhun lawọn yoo ti pa fun oṣu mẹta gbako.

Ninu atẹjade ọhun ti Alaaji Hammed Ganiyu, to jẹ asaaju fẹgbẹ idagbasoke fawọn ọdọ ni Ipẹru- Remọ, ni wọn tun ti fi aidunnu wọn han bi wọn ṣe sọ ilu naa sinu okunkun biribiri ati bi aabo tun ṣe mẹhẹ.

Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn ti fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti lori igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe yii, wọn waa n fẹ ifọwọsowọpọ awọn ọlọpaa lori igbesẹ wọn yii.
Awọn ọdọ ilu naa tun ke si awọn alaabo ilu lati  ṣiṣẹ lori eto abo niluu ọhun pẹlu awọn nnkan to ṣẹlẹ lagbegbe yii lẹnu ọjọ mẹta.
A o ranti pe lẹnu ọjọ mẹta yii ni wọn ji awọn meji kan gbe bẹẹ ni wọn tun pa ọjọgbọn kan nileewe giga yunifasiti Babacok to wa ni Iliṣan.
Wọn wa fi  akoko naa rọ ẹgbẹ idagbasoke Ipẹru labẹ aṣaaju wọn Oloye Jide Oyeti ati igbimọ lọbalọba paapaa Alaperu tilu Ipẹru, Oba Adeleke Adelekan Idowu Basibo Odoru atawọn Baalẹ fun atilẹyin wọn lori igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe yii.
Bakan naa ni wọn tun ke si Gomina Dapọ Abiọdun lat ba wọn da si ọrọ naa

No comments:

Post a Comment

Pages