Wọn ṣe ifilọlẹ ajọ tuntun ti Ajadi Oguntoyinbo niluu Ilaro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 5 February 2024

Wọn ṣe ifilọlẹ ajọ tuntun ti Ajadi Oguntoyinbo niluu IlaroLọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni wọn ṣagbekalẹ ajọ tuntun kan eyi ti wọn pe ni 'Ajadi New Era Foudation' niluu Ilaro.

Nibi eto ọhun lawọn eeyan ti tu jade si gbọgan ti ayẹyẹ ọhun ti waye nibi ti wọn ti fi idunnu wọn han lati fọwọsowọpọ pẹlu ajọ tuntun ti wọn fi pe ori Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo.

Ninu ọrọ Arabinrin Funmilayọ Ọdunẹyẹ, nibi eto naa lo ti ṣalaye idi ti wọn fi gbe ajọ naa kalẹ. O sọ pe pataki ẹ ni lati dide iranlọwọ fawọn araalu nipasẹ ironilagbara.

Bẹẹ lo sọ pe ilu Ilaro to jẹ ilu Ajadi Oguntoyinbo lawọn ti kọkọ waa gbe iru eto bẹẹ kalẹ pẹlu ileri pe gbogbo igun mẹtẹẹta to wa nipinlẹ Ogun ni wọn yoo tan imọlẹ ẹ de.

Arabinrin Funmilayọ tun ṣalaye pe ki i ṣe nitori oṣelu lawọn fi da ajọ naa silẹ lakooko yii bi ko ṣe lati gba awọn ọmọ ipinlẹ Ogun silẹ ninu iya oun ipọnju.

Ninu ọrọ Kọmureedi Olowu, to jẹ alukoro fẹgbẹ oṣeṣu NNPP nipinlẹ Ogun lo ti ki gbogbo awọn ọmọ ilu Ilaro ku oriire lori bi wọn ṣe da ajọ Ajadi ọhun silẹ.

Bẹẹ lo fi aidunnu ẹ han bi nnkan ṣe n lọ lorileede yii nipa bi nnkan ko ṣe lọ bo ṣe yẹ. Ninu ọrọ ẹ lo ti sọ pe ara nni awọn araalu pupọ, kaka ko dẹ, ṣe lo ni o n le koko.

O waa gba awọn to wa nibẹ lamọran lati bẹrẹ si nii polongo ajọ tuntun naa fawọn araalu, nitori ẹni to nii ṣetan lati dide iranlọwọ fun gbogbo araalu.

Bẹẹ lo ṣapejuwe Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, to ni ajọ naa gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu, to maa n dide iranlọwọ lọpọ igba. 

Lẹyin eyi lawọn araalu beere awọn ibeere lati mọ nipa ajọ tuntun ọhun.Laipẹ yii la gbọ pe iru eto bẹẹ yoo tun waye ni agbegbe Ijẹbu.

No comments:

Post a Comment

Pages