Gbogbo aye lo ṣedaro Jimi Ṣolankẹ, Baba Agba to dagbere faye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 5 February 2024

Gbogbo aye lo ṣedaro Jimi Ṣolankẹ, Baba Agba to dagbere faye



Lati ana, ọjọ Aje, Mọnde, ti iroyin ti gba igboro pe ọkan lara awọn to n gbe aṣa ilẹ wa, to tun jẹ agba ọjẹ nidii iṣẹ orin ati ere ori itage, Alagba Jimi Ṣolankẹ, tọpọ mọ si Baba Agba, ti jade laye lawọn eeyan ti bẹrẹ si nii daro.

Ọsibitu yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, ni wọn sọ pe baba naa ti dagbere faye laaarọ ana.
Ohun ta a tiẹ gbọ ni pe Alagba Ṣolankẹ ṣi ṣe ipade pọ pẹlu awọn kan ni alẹ o ku ọla ti yoo ku yii.

Ọjọ kẹrin, oṣu keje, ọdun 1942, ni wọn bi Baba Agba ni Ipara-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun. O  darapọ mọ ẹgbẹ tiata Orisun theare group, eyi ti Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, da silẹ lọdun 1961.

Ọpọ awọn ere ori itage oloyinbo ni Ṣolankẹ kopa ninu ẹ nigba to wa laye. O si tun maa fi orin pa alọ fawọn ọmọ kekere. Odu ni ki i ṣaimọ foloko lorileede yii ati ni oke-okun.

Latigba ti iroyin ipapoda ẹ ti gbode lawọn eeyan ti n ranṣẹ ibanikẹdun lara wọn ni Gomina Dapọ Abiọdun, ẹni to ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ akọni nla lawujọ.

O sọ pe ipa Alagba Jimi Ṣolankẹ, ko le ṣe gbagbe ninu itan orileeede yii ati pe adanu nla lo jẹ.

  O waa ba gbogbo ọmọ orileede yii kẹdun ẹni rere to lọ.

No comments:

Post a Comment

Pages