Sanyaolu di alaga fẹgbẹ apapọ oloṣelu IPAC nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 27 February 2024

Sanyaolu di alaga fẹgbẹ apapọ oloṣelu IPAC nipinlẹ Ogun.



Abayọmi Sanyaolu, alaga fẹgbẹ oṣelu AA nipinlẹ Ogun ni wọn ti dibo yan an wọle fun alaga ẹgbẹ oloṣelu lapapọ nipinlẹ naa iyẹn IPAC.

Nibi ibo ẹgbẹ ọhun to waye niluu Abẹokuta lanaa ni ọkunrin naa ti fẹyin Okusanya Samson, to ti wa nipo ọhun gbolẹ pẹlu ibo mẹwaa si meje.

Ninu ọrọ ẹ lẹyin ti wọn ṣebura fun un lo ti fi ẹmi imoore ẹ han si Gomina Dapọ Abiọdun lori bo ṣe faaye gba eto oṣelu ti ko si ẹlẹyamẹya.

O sọ pe igba ọtun ti de ba oṣelu nipinlẹ Ogun pẹlu ileri pe oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu gbogbo ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, ki aṣéyọri fi le tunbọ ba wọn.

Bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ awọn oloye ẹgbẹ IPAC, lapapọ ati ajọ eleto idibo fun bi wọn
ṣe ṣeto ibo ọhun ni irọrun.

Awọn oloye ẹgbẹ yooku ni Jagun Lukman, igbakeji alaga,Amb. Yeye Olufunke Olanrewaju, akọwe, Dr. Yinka Williams, igbakeji akọwe,Afọlabi Adeṣina,akapo atawọn yooku


  

    .     

No comments:

Post a Comment

Pages