Olu Itori ti bẹrẹ ayẹyẹ ogun ọdun to gori itẹ awọn babanla ẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 22 February 2024

Olu Itori ti bẹrẹ ayẹyẹ ogun ọdun to gori itẹ awọn babanla ẹOlu tilu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ, ti rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati ma ko ẹ̀bi, bi ọrọ aje ṣe dorikodo lakooko yii le Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori, nitori pe nnkan tijọba rẹ ba lọwọ awọn to gbe e silẹ, lo ti bajẹ jinna.

 

Ọba naa sọrọ yii nibi ipade oniroyin to waye fun ti ayẹyẹ ogun ọdun to fẹẹ ṣe, eyi ti wọn ti bẹrẹ bayii. O sọ pe gbogbo ọna ni Aarẹ Tinubu n gba lati rii pe nnkan rọrun fun araalu amọ omi ti pọ ju ọka lọ.

 

O gba awọn araalu nimọran lati dakẹ lori bi wọn ṣe n sọ ọrọ kobakugbe sijọba to wa lode naa, nitori ipenija to ni Aarẹ koju yii lati ọdọ awọn ti wọn gbe jọba silẹ fun-un lo ti wa.

 

O ni kaka bẹẹ ṣe ni ki wọn maa fi adura ran ijọba naa lọwọ ati atilẹyin to gbookan, awọn nnkan wọnyii lo sọ pe o le mu aṣeyọri ba Tinubu. Bẹẹ lo tun gboriyin fun Tinubu lori bijọba ẹ ṣe yọ owo afikun tijọba maa fi lori owo epo iyẹn sọbsidi, o ni igbesẹ to dara ni lati le mu ki ọrọ aje le ni itẹsiwaju.

 

Kabiyesi tun sọ pe’’ Ohun ti mo fẹẹ ki gbogbo awọn ọmọ orileede yii mọ daju ni pe Aarẹ Tinubu jogun, ipọnju yii lati ọdọ ijọba to gbe e silẹ. A kan ni lati maa fi adura ran-an lọwọ. Meloo ninu wa lo ji lowurọ kutu, to sọ ki Ọlọrun bukun Naijiria, kaka bẹẹ ọrọ odi ni yoo maa jade lẹnu wa’’

 

‘’ Ko si ibomii-ii taa ni ju orileede wa yii lọ, ajo ko si dabi ile, nitori idi eyi, ẹ jẹ ki a nipa pataki lati ko lati kọju ija si ìṣẹ́ oun òṣì yii. Ni nnkan bi aadọta si ogoji ọdun sẹyin, ọlọro nla ni wa, nitori a nigbagbọ ninu iṣẹ ọgbin’’

 

‘’ Sibẹ naa, ẹ si jẹ ka kan saara si Aarẹ Tinubu lori bo ṣe yọ owo sobsidi, nnkan gidi to ti ṣe. Ni temi, ẹ jẹ ka ṣe suuru, mo si nigbagbọ pe gbogbo nnkan yoo si pada bọ sipo rere’’

 

Bẹẹ naa ni Olu Itori tun lo akoko ọjọ naa lati fi ẹmi imoore han si Gomina Dapọ Abiọdun lori akitiyan ẹ lori titun ọna Sango si Abẹokuta ṣe, eyi to ṣaaba maa n dẹnukolẹ lakooko ti ojo ba n rọ.

 

Fun ti ayẹyẹ ogun ọdun naa ni Kabiyesi ti sọ pe awọn yoo tun lo akoko naa lati fi dẹrin pa awọn to ku diẹ fun lawujọ. O ni o kere ju apo aadọta baagi irẹsi,ẹwa, gaari, ni o ti wa nilẹ lati pin fun wọn lagbegbe Itori.

 

O sọ pe oun ṣe eleyii lati fi ko ipa toun lori bi iya ṣe n jẹ awọn eeyan kan niluu, bẹẹ lo  tun ṣeleri ẹrọ amunawa igbalode, sola, aaadọta le nigba, ti wọn yoo pin lọjọọru, Wẹsidee, ọsẹ to n bọ.Bẹẹ ni ayẹwo oju lọfẹẹ fawọn ẹẹdẹgbẹta to n gbe agbegbe naa. Pabanbari ẹ ni ti Dokita Saheed Oṣupa ti yoo fere da awọn lọla

 


No comments:

Post a Comment

Pages