Gómìnà Abíọ́dún yẹ̀yẹ́ Adébutú, ó ní kó múrasílẹ̀ fún àtúndì ìbò lọ́dún 2027 - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 19 January 2024

Gómìnà Abíọ́dún yẹ̀yẹ́ Adébutú, ó ní kó múrasílẹ̀ fún àtúndì ìbò lọ́dún 2027



 

Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, ti fi oko ọrọ ranṣẹ si Ọnarebu Ladi Adebutu,oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ninu ibo to waye lọdun to kọja, lati ṣe suuru di ọdun 2027, ki o si gbaradi fun atundi ibo toun atawọn eeyan ẹ n beere fun.

 

O sọrọ yii ni papa ofurufu Gateway International, to wa ni Ipẹru-Rẹmọ, lẹyin to pada de lati Abuja, nibi to ti jawe olubori nile -ẹjọ giga ju fun ti ibo gomina to waye lọdun  2023.

 

Bẹẹ lo waa sọ pe akoko ti to bayii lati kọjumọ awọn iṣẹ idagbasoke, nitori gbogbo ọna lati le ma jẹ kijọba oun fọkan si isakoso oun ti kuna nitori bi oun ṣe jawe olubori ọhun.

 

Gomina sọ pe, Ireti waa ni pe gbogbo awọn alatako wa ti wọn pariwo pe ki atundi ibo waye le maa murasilẹ fun ọdun 2027. Niitori aṣeyọri yii ti fopin si gbogbo ọrọ ile-ẹjọ lati ọdun 2018''

 

Bẹẹ lo wa ṣeleri pe ijọba oun yoo wa kọjumọ fifi awọn apẹẹrẹ rere lelẹ ati pe lati wakati yii lọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun, yoo bẹrẹ si jẹ anfaani mudunmudun ijọba pẹlu awọn eto rere to nii fun wọn.

 

Bakan naa lo waa fi idunnu ẹ han si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu,fun atilẹyin to ṣe foun  lori irianajo oṣelu oun, bẹẹ naa lo tun dupẹ lọwọ ikọ awọn agbẹjọro ẹ, eyi ti Oloye Wọle Ọlanipẹkun ṣaaju fun.

 

O tun fi ẹmi imoore ẹ han si alaga ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ, Ọmọwe Abdulahi Umar Ganduje ati tipinlẹ Ogun, Oloye Yẹmi Sanusi, fun atilẹyin wọn ti o n ri gba latigba ti ọrọ oṣelu ti bẹrẹ.

 

Gomina Abiọdun tun dupẹ lọwọ igbimọ ẹlẹni marun-un ile ẹjọ giga julọ, eyi ti Onidajọ agba John Inyang Okoro, ṣaaju, igbimọ to gbẹjọ naa nipinlẹ Ogun ati nile ẹjọ kotẹmilọrun lori bi wọn ṣe ẹni tawọn eeyan n fẹ ko jẹ gomina wọn.

 

No comments:

Post a Comment

Pages