Ọgbẹni Olowu Olayẹmi Ọmọkẹhide, to jẹ alukoro fẹgbẹ oṣelu NNPP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ko sẹni to ran Ọgbẹni Sunday Ọginni to ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ ọhun ni atẹjade to gbe e jade to fi ki Gomina Dapọ Abiọdun ku oriire jijawe olubori nibi igbẹjọ ile ẹjọ giga to waye.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, lo ti sọ pe bigba to fẹẹ maa fi orukọ ẹgbẹ yii lu jibiti, nitori pe awọn ti da a duro ninu ẹgbẹ ọhun nitori awọn aṣemaṣe to ṣee lọdun to kọja lakooko ibo to waye.
Olowu tun fẹsun kan Ọginni lori bo ṣe sọ ara ẹ di akọwe ẹgbẹ naa lapapọ, ni eyi to jẹ pe ẹgbẹ kọ lo yan an sibẹ.
O sọ pe iyalẹnu lo jẹ fawọn nitori bi ọkunrin naa ṣe fọgbọn eeru ṣiṣẹ ti wọn ko ran an lori idjajọ ile ẹjọ giga to da Gomima Dapọ Abiọdun lare.
O waa rọ awọn araalu ati ijọba ipinlẹOgun lati ma ṣe ka atẹjade naa si, nitori pe ki i ṣe ẹgbẹ NNPP lo ran niṣẹ to jẹ.
Olowu tun fikun ọrọ ẹ pe ki i pe awọn tako idajọ to da Dapọ Abiọdun lare o, amọ ki i ṣẹnu Ọginni lo yẹ ko ti jade,nitori ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa mọ..
Gẹgẹ bo ṣe wi awọn ojulowo ọmọ ẹgbẹ ni wọn wa labẹ alaga wọn lapapọ iyẹnAbba Kawu Ali. Bẹẹ lo sọ pe Ọlayọku ni akọwe ẹgbẹ naa lapapọ.
O ni ko seni ti ko mo Ọginni atawọn eeyan ẹ bi ẹni to n ta ẹgbẹ fawọn oloṣelu mii in,o ni okoowo ni wọn maa fi oṣelu ṣe.
Olowu waa pari ọrọ ẹ lati gba ijọba ipinẹ́ Ogun lamọrn lati koju ipenija tawọn araalu n koju lakooko yii
No comments:
Post a Comment