Àwọn afurasí ọlọ́pàá mẹ́rin táwọn ajagungbalẹ̀ ń lò láti dúnkokò dèrò àtìmọ́lé - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 11 January 2024

Àwọn afurasí ọlọ́pàá mẹ́rin táwọn ajagungbalẹ̀ ń lò láti dúnkokò dèrò àtìmọ́lé



Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ti mu awọn afurasi ọlọpaa mẹrin kan si atimọle lori ẹsun pe wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajagungbalẹ lati maa dunkoko mọ awọn eeyan lori ilẹ wọn, bẹẹ ni wọn sọ pe wọn tun gbowo oṣu lọwọ wọn pẹlu.

 

Gẹgẹ bi iwadii wa, ohun to ṣokunfa mimu awọn afurasi ọlọpaa naa ko ṣe lẹyin iwe ẹsun ti wọn ni ẹbi kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Aidokun-Ogbo, ni Ewupẹ, nipinlẹ Ogun, kọ nibi ti wọn ti fẹsun kan awọn eeyan naa pe wọn gba ki awọn ajagungbalẹ maa lo wọn tako awọn eeyan lori ilẹ wọn to wa ni Ọta.

 

Awọn afurasi mẹta ọlọpaa mẹta ninu awọn mẹrin, la gbọ pe ọwọ kọkọ tẹ lori bi wọn ṣe n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹbi Ajibọdẹ, torukọ wọn jẹ Yusuf Ajibọde, Karimu Ajibọde, Oloye Rami Ajibọde, Oloye M.A. Ajibọdẹ ati John Ayinde.

 

Ninu iwadii lati ọdọ awọn ọlọpaa, tun sọ pe ẹbi Aidokun, Ewupẹ, lọ kọ lẹta ifiẹsun kan ni sawọn ọga ọlọpaa patapata loriledee yii lori bi awọn ajagungbalẹ yii pẹlu atilẹyin awọn ọlọpaa kan lati maa fi da wahala silẹ lagbegbe naa.

 

Wọn sọ pe ileeṣẹ agbẹjọro kan ti wọn pe ni El-Shagala Consults, lo kọ iwe ifẹsun kan ni ọhun lorukọ Dauda Gbadamọsi, Ọmọọba Sadiku Ọbalanlege,

Yisa Akinbọtede ati Muraina Abatan lorukọ gbogbo ẹbi Aidokun-Ogbo, Ewupẹ, ti wọn rọ ọga ọlọpaa patapata lati tete ba wọn da si wahala naa.

 

Wọn ni lẹta yii lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ṣiṣẹ lee lori, ti wọn fi mu awọn afurasi ọlọpaa naa. Nnkan ti wọn lawọn lo n bi ẹbi naa ninu ni bi wọn ṣe ni awọn ajagungbalẹ ti wọn fẹsun kan naa ṣe parọ pe awọn ti gba idalare lati ile ẹjọ.

 

Bẹẹ la tun gbọ pe awọn ti wọn fẹsun kan naa ti gbe awọn lọ sile ẹjọ lati ile-ẹjọ giga de kotẹmilọrun, to si jẹ pe awọn jare bọ. Wọn ni nigba ti ko tẹ wọn lọrun, ni wọn bẹrẹ si ni ṣe idajọ lọwọ ara wọn, ti wọn n wọ ilẹ onilẹ lọna aitọ, ti wọn si dunkoko mọ wọn pẹlu.

 

A gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn afurasi oṣiṣẹ wọn ti wọn fẹsun kan naa pẹlu ileri pe idajọ ododo yoo waye.

 


No comments:

Post a Comment

Pages