Adebanjọ Adeọla ni yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Labour nibi ibo aṣoju-ṣofin Surulere kin-in-ni niluu Abuja - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 7 January 2024

Adebanjọ Adeọla ni yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Labour nibi ibo aṣoju-ṣofin Surulere kin-in-ni niluu Abuja



Onimọ ẹrọ Adebanjọ Adeọla ni o jawe olubori gẹgẹ bi ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Labour, fun ti ibo aṣoju-ṣofin ẹkun Surulere kin in ni, nipinlẹ Eko, ti yoo waye ninu oṣu keji ọdun yii.

Ọkunrin naa jawe olubori nibi ibo abẹle ẹgbẹ naa to waye lagbegbe Mọdele, lọna Tẹjuoṣo, Barrack, nipinlẹ Eko, nibi ti ajọ to n ṣeto ibo lorileede yii iyen INEC, ti ran aṣoju wa sibẹ.

Awọn mẹta ni wọn dije fun ipo naa, nibi tawọn aṣoju mẹta mẹts ti wa lati agbegbe mẹfa ti wọn wa labẹ ẹkun naa.

Bo tilẹ jẹ pe alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Pasitọ Dayọ Ekong, ko si nibẹ lọjọ naa nitori awọn akanṣe iṣẹ kan ti wọn sọ pe o lọọ ṣe sibẹ akọwe ẹgbẹ naa, Sam Okpala ati ọkan lara awọn oloye wọn lati Abuja.

Lẹyin ti wọn dibo tan ni wọn kede Adebanjọ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo mejila ninu mejidinlogun ti wọn di lọjọ naa.

Ninu ọrọ ẹ lẹyin ti wọn fa ọwọ ẹ soke, Onimọ ẹrọ Adebanjọ dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lori bi wọn ṣe fun un ni tikẹẹti fun ibo to n bọ naa pẹlu idaniloju pe oun yoo jawe olubori.

Bẹẹ lo rọ awọn ti wọn jọ dije lati jọ ṣiṣẹ pọ, ki wọn si jọ wa nisọkan ki wọn le gba ipo naa lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC, to ti wa nibẹ tẹlẹ.

A o ranti pe Ọnarebu Fẹmi Gbajamila ti ẹgbẹ APC, lo jawe olubori nibi ibo naa tẹlẹ to waye ninu oṣu keji ọdun to kọja ṣugbọn ti wọn kede pe ipo naa ṣofo lẹyin to gba lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ aarẹ lorileede yii.

No comments:

Post a Comment

Pages