Obesere, Eedris Abdulkareem atawọn olorin mii-ii fẹẹ ṣere ọdun fun Bullion Go-Neat Global - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 30 December 2023

Obesere, Eedris Abdulkareem atawọn olorin mii-ii fẹẹ ṣere ọdun fun Bullion Go-Neat Global


 




Gbogbo eto lo ti to bayii fun ariya ọdun, eyi tileeṣẹ Bullion Go-Neat Global, labẹ oludari Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, ṣagbatẹru ẹ, ti yoo waye lọjọ Kin-in- ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2024, to bọ si ọjọ Mọnde, ọsẹ to n bọ.

 

Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sọwọ si wa ọpọ awọn gbajumọ olorin lo n bọ waa fere da awọn eeyan lọla. Lara wọn Alaaji Abass Obesere , tọpọ mọ si PK1st, Eedris Abdulkaree, Femo Lacasta, Baba Labule, Alafin Bẹbẹto, Ọtun Muri Thunder, MC Kirikiri, Ronkẹ Oṣodi oke atawọn mii-ii

 

Ariya ọhun ti wọn pe ni Jam Street ni yoo waye ni Torotoro, Ọrẹmeji niluu Ibafo, nipinlẹ Ogun. Bẹẹ ni oriṣiriṣi ẹfẹ yoo tun waye lọjọ naa.

 

Gẹgẹ bi Ambasedọ Olufẹmi Oguntoyinbo, to jẹ oniṣowo nla, to tun tu figba kan dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP, nipinlẹ Ogun, ṣe wi, o lawọn maa n ṣeto ọhun lọdọọdun lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ipamọ oore rẹ.

 

Okunrin to gba ami ẹyẹ ‘Man of the Year’’ laipẹ tun sọ pe lara ileri oun ati ifẹ toun tun ni si igbelarugẹ orin ni lati maa ṣeto yii lọdọọdun, eyi to sọ pe igba akọkọ kọ ree tawọn yoo ṣeto iru nnkan bẹẹ.

 

Bakan naa lo lo anfaani yii lati fi dupẹ lọwọ gbogbo awọn onibaara atawọn oloolufẹ ẹ jakejado orileede yii, fun ifẹ ti wọn ni si oun pẹlu ileri pe ileeṣẹ oun ko nii ja wọn ni tan-an mọ.

No comments:

Post a Comment

Pages