Gọngọ sọ niluu Abẹokuta lọjọ ti ajọ alaaanu ọkọ opo fawọn opo ni ẹbun ọdun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 29 December 2023

Gọngọ sọ niluu Abẹokuta lọjọ ti ajọ alaaanu ọkọ opo fawọn opo ni ẹbun ọdun



O tipẹ ti ariwo ti n lọ lọtun, losi pe, oludasilẹ ileeṣẹ to n ta ilẹ iyẹn Pelican, Ọmọwe Tunde Adeyẹmọ, da ajọ alaaanu kan silẹ, eyi to pe ni ‘Ọkọ Opo’’ nibi to ti pinnu lati maa ṣetọju awọn to ba jẹ opo, lati le mu inu wọn dun.

 

Ṣugbọn lọjọ keji ọdun keresi ni ifilọlẹ ajọ naa waye, nibi tawọn opo to le ni ọgọrun-un ti mu ẹbun lọ sile,bi wọn ṣe fun lounjẹ lọjọ naa bẹẹ ni wọn tun mu owo lọ sile pẹlu, bẹẹ ni adura pe adura ranṣẹ tawọn to jẹ anfaani ninu eto ọhun ṣe fun oludasilẹ ajọ naa.

 

Eto ọhun to waye nileeṣẹ Pelican Valley Estate, Laderin, niluu Abẹokuta, lawọn opo naa tun ti jẹ anfaani ayẹwo ilera lọfẹẹ, ti wọn si tun gba wọn niyanju lori bi wọn ṣe le maa tọju ara wọn, ki wọn le maa ji pepe.

 

Alaaja Sidikat Adeyẹmọ, to jẹ Iya Adinni, mọṣalasi agbegbe Ginti, Ikorodu, to tun jẹ Mama fun ẹni ti ṣagbatẹru eto ọhun, toun naa jẹ opo lo anfaani ọjọ naa lati fi sọ iriri ẹ lati le fi gba awọn opo nimọran lọjọ naa lati sunmọ Ọlọrun, ki wọn si maa rii pe wọn wa nnkan ṣe, ki wọn fi le maa jẹ eeyan.

 

Bakan naa ni agba ọjẹ nidii iṣẹ iroyin, Oloye Eddy Aina naa rọ awọn opo yii lati ma ṣakiyesi lori ọjọ ori, ipo ilera, ati bi wọn ṣe ri lakooko, pẹlu imọran pe awọn mii-in ti wọn ti kọja ogoji ọdun soke, gbọdọ maa jẹ ẹfọ, awọn nnkan eleso, ọgẹdẹ ti ko pọn, ẹja tabi ede, iyọ,, gaari irẹsi, amala, iṣu ko gbọdọ maa pọju nitori ṣuga.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, o bi ọjọ ori wọn ba ṣe n lọ soke ni agba yoo maa lawọn agọ ara yoo ti ma kọ awọn ounjẹ, to le mu ki ifunpa maa ga, tabi ki eeyan ni itọ ṣuga atawọn aisan pẹpẹpẹ ẹ mi.

 

O ṣalaye siwaju pe pẹlu osuwọn oun, awọn opo miliọnu mẹẹẹdogun ni wọn wa lorileedw tii,  pẹliu aidunnu pe ọpọ wọn lo jẹ apa South-East ni wọn pọ si, bẹẹ lo rọ ijọba apapọ lati fọwọsowọpọ pẹlu Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ lati ran an lọwọ ki igbogun ti oṣi ati ipọnju ko le dinku laarin awọn opo lorileede yii.

 

Ninu ọrọ Ọgbẹni Lekan Jaji, to jẹ onkọwe, toun naa sọrọ lọjọ naa, sọ pe kawọn opo naa gba gbogbo nnkan to ba ṣẹlẹ si wọn, ki wọn si gba pe oloolufẹ wọn to ti lọ, ko tun le pada wa mọ.

 

O sọ pe gbigba fun Ọlọrun yii yoo tun jẹ ki awọn opo gan-an tẹsiwaju nipa irin ajo aye,ko si ni jẹ ki ironu wọnu ọkan wọn ti yoo ma mu wọn ṣe nnkan ti ko yẹ ki wọn ṣe.

 

Eto ọhun to ti kọkọ gba wọn niṣẹju marundin laadọta, ni fifi ọrọjomitoro ọrọ ti waye pẹlu alaṣẹ ati igbimọ ajọ naa. Awọn naa ni Ọmọwe Babatunde Adeyemọ, Ọgbẹni Adeyẹmo Ibrahim; akọwe ajọ naa, Arabinrin Titilayọ Babs Adeyẹmọ, alakoso, ati Ọgbẹni Olukayọde Ọlasẹhinde, Ambasedọ ajọ alaaanu Ọkọ Opo. 

 

 

Awọn oniroyin  ti wọn dari eto naa ni Oloye Eddy Aina, Ọgbẹni Tọpẹ Adaramọla ati Ernest Nwokolo, akọroyin lati ileeṣẹ iwe iroyin The Nation.

 

Nibẹ ni Ọmọwe Adeyẹmọ, ti fi idunnu ẹ han lori aṣeyọri ifilọlẹ ajọ alaanu ọkọ opo, pẹlu bawọn opo ṣe jade. O ni o jẹ ki erongba lati le ṣe nnkan rere lorileede yii ayi ayipada fun iru idasilẹ nnkan bẹẹ.

 

Bẹẹ lo tun ṣalaye pe erongba idasilẹ ọkọ opo yii jẹ majẹmu ti oun ni pẹlu Ọlọrun. O tun sọ di mimọ pe miliọnu lọna aadọjọ Naira, iyẹn N150m loun ti gbero silẹ fun iṣẹ akanṣe naa lati bi ọdun mẹwaa sẹyin, pẹlu afikun oun fẹẹ fi eeka ilẹ meji lati fi pese ile fawọn opo to ku diẹ kaato laarin wọn.

 

Nigba to sọ iriri ẹ ati idi to fi gbe eto naa kalẹ, Ọmọwe Adeyẹmọ sọ pe, ‘ Agbekalẹ ajọ yii nnkan kekere ni lati le jẹ ki nnkan waye lorileede lati fi yi nnkan pada. Mo wa lati idile to jẹ pe awa naa jẹ iya pupọ. Alaaanu ni baba mi, to si jẹ oṣiṣẹ ijọba, ọdun mẹtadinlọgbọn to fi ṣiṣẹ, ko kọle fun ara ẹ. Ṣe lo maa n lo owo to ni lati ro awọn eeyan lagbara. Koda. Niluu ti mo ti wa, ọpọ awọn eeyan lo ran lọwọ, ran wọn lọ sileewe. Ẹ ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu pe nigba to fẹyinti lẹnu iṣẹ, ile ti wọn ko tii kọ pari la ko lọ, ta a mọ ẹni to ni, ko si ina, ilẹkun ati ferese, fun ọpọ ọdun’’.

 

 

"Ohun lo jẹ ki n ni anfaani lati mọ nipa awọn igbo to wa ninu oko, ọpọ ẹ lo si ti di ilu, oun gan an lo jẹ ki emi naa da ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited silẹ.  Ati pe oun kan ti mo tun kọ lọdọ baba mi ni pe ko si owo naa to ni to le fun ọjọ iwaju ara ẹ ati ti ọmọ ẹ, ọna naa to le gba tọju owo ni lati na sori awọn iṣẹ, na sori awọn eeyan.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages