Mákindé Fásunlé ṣẹ bẹbẹ nibi ayajọ Owuyẹ l'Ekoo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 3 December 2023

Mákindé Fásunlé ṣẹ bẹbẹ nibi ayajọ Owuyẹ l'Ekoo

 
 

Gbajumọ olorin juju nni, to tun jẹ ọga agba pata nileeṣẹ redio Fresh FM, Yinka Ayefẹlẹ dabira lọjọ ti ọkan lara awọn to maa n ṣeto lori redio ẹ yii, Oloye Makinde Fasunle, tọpọ mọ si Sẹnetọ, ṣayẹyẹ ayajọ Owuyẹ, nibi tawọn eeyan jakanjakan lawujọ ti peju pesẹ.

 

Owuyẹ gẹgẹ bi Makinde Fasunle ṣe sọ, ni eto to maa n ṣe lori redio to jẹ tileeṣẹ Fresh FM, to wa kaakiri, eyi to sọ pe oun ti bẹrẹ ni nnkan bi ọdun mẹjọ sẹyin. Bo tilẹ jẹ pe nnkan bi ọgbọn ọdun o le diẹ sẹyin lo ti bẹrẹ iṣẹ sọrọsọrọ. 

Ọkunrin naa sọ pe owuyẹ jẹ eto toun ti maa n sọ iriri nnkan to ṣẹlẹ lawujọ, eyi to kun fun ọpọ ipenija ninu amọ ti Ọlọrun ko oun yọ. O ni meloo loun fẹẹ sọ nipa awọn iṣẹlẹ kayeefi toun ti sọ jade ati bawọn kan ṣe fẹẹ tipasẹ ẹ ji oun gbe.

 

O waa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun. Ninu ọrọ Yinka Ayefẹlẹ lo ba Fasunle dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun sọrọsọrọ to fun un, agba ọjẹ lo pe e nidi iṣẹ naa. Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa Ẹrẹkẹ ni ṣọọbu ati Alajẹju, tawọn naa da awọn eeyan lara ya. 

Lara awọn eto ti wọn ṣe lọjọ naa jijẹ ẹbun mọto lọfẹẹ, eyi ti obinrin kan to n ta pọfupọfu gbe lọ sile, bẹẹ lawọn mi-ii naa tun mu ẹbun

  lọ sile nibi idije tẹtẹ oriire to waye.

 

Bakan naa ni wọn tun lo akoko naa lati fi ro awọn to ku diẹ kaato lagbara pẹlu ẹbun owo ati fi fawọn eeyan kan ni ami ẹyẹ fawọn ipa

 ti  wọn ko lawujọ.

No comments:

Post a Comment

Pages